30/06/2025
Ọdún ọmọ Ejio, Ayọ̀ ọmọ Ọbàlọràn, Àkànnàmọ̀gbò kìí pọdún jẹ,
Emi Ọlálékan aa pẹ́ láyé bí ewé àpẹ́, Pípẹ́ ni ti pẹ́pẹ́ nígbó, Pípẹ́ ni bàtà ń pẹ́ lẹ́sẹ̀ pẹ́pẹ́yẹ, Kánrinkéṣe ni Èṣù ń pẹ́ lójú òde,
Ọ̀pọ́n kò ní sé kankan
Òkùtẹ̀ kò ní yẹ̀ bọ̀rọ̀bọ̀rọ̀
Omi agbada kò ní dànù wàràwàrà
Asodun modun niisawo asodun modun,
Asosu mosu níí ṣawo asosu mosu,
Ọdọọdún láárí orógbó
Ọdọọdún láárí awùsá,
Ọdọọdún láárí ọmọ obi lórí àtẹ
Ọdọọdún ni s'apo nruwe
Ọdọọdún ni peregun ni láṣọ maso
Igúnnugún kii kuu l'ewe ma kasai d'arugbo
Akalamagbo kii podun jẹ mio nii pàá odun jẹ
Ọparun jegejege awo inú igbó
Ọparun jegejege awo ilu odán
Òràn ni mo se, nkó ṣe iku
Aimọ orúkọ ikú kò pani
Aimọ orúkọ àrùn, ko gbenide,
Aimọ orúkọ asasi ko muni,
Aimọ orúkọ ẹbọ kafoju jebo,
Aimọ orúkọ idagiri ko dani lojiji,
Aimọ orúkọ iṣẹ Alfa ko pani níye mọlẹ,
Wolojo olukaye afere npete lórúko ti won npe iku , iku o ni mi pàá .
Olarinako ọrọ abasomola lórúko ti won npe àrùn, àrùn o nimi se
Ẹfufulele semolese túmọ nínú teruteru loruko ti a npe asasi, asasi o nimi muu.
Olongbo dúdú etí àjà lórúko ti won npe idagiri, idagiri o ni dáa mi
Oojia oke oríta lórúko ti won npe ẹbọ, mío ni foju kẹbọ.
Baba imọle won o gbamu dodo ki won o too pon'mi wẹ lórúko ti won npe iṣẹ Alfa , iṣẹ Alfa o nimi se e
Adétuka loruko ti won npe ẹfun,
Aderinaka lórúko ti won npe eedi
Ẹfun ma fún mi , eedi o gbọdọ dimi,
Èlà ìwòrì ! Èlà ìwòrì!! Èlà ìwòrì !!!
Ma je ki Emi Ọlálékan omo Adepọju o r'ogun àgbákò óò! Ela ìwòrì !!
Aja dúdú morongbogbo nigbo alaja Kooro, Opaakaka ni dari olóde nígbó alájá ilẹ,
Awọn méjèèjì lo ṣefa fún orumilá lójó tí wọn nperi baba níbi.
Ọrunmila ni ẹni toba perí oun níbi, ọsán gángan ni idagiri nda nile ikú, kutukutu ni a ngbo iku ewuju ,
Osangangan langboku òòrè,
ọrọ bi àkàsù kii tan loro ẹkọ
Ọrọ bi iku òjìji ko ni won nile awọn ọta mi.
Happy birthday to me ASOOREGESIN!