17/10/2023
ASIRI NIPA IGBIN (SNAIL)
Igbin jẹ eranko igbó ti o fẹràn lati ma gbe ibi ti o tutu púpọ bẹni ọpọ eniyan ni o yan igbin layo gẹgẹ bí ohun-ọsin.
O jẹ eranko tí kò tóbi rara sugbon o jẹ ẹran ti ọpọlọpọ eniyan fẹràn lati ma jẹ nitori o ma ndún púpọ.
Ọpọlọpọ ohun asiri (ogun) ni awọn alagbara má nfi igbin se ṣugbọn mo fẹ sọ diẹ ninu iṣẹ ibi ti awọn ika eniyan ma nfi eranko igbin se sí eniyan.
1. Awọn alagbara ika eniyan ma nfi igbin sa ogun ifasẹhin sí eniyan.
Ẹnití wọn ba sa ogun ifasẹhin sí, iru ẹni bẹ le ma he igbin loju orun rẹ.
Iru ẹda bẹ, dipo ti iba ma fi ni itẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ, yíò kan ri wipe nkan dàrú beni iṣẹ rẹ yíò padà ma lọ sẹhin.
2. Eniyan ti won ba fi igbin sa iṣẹ búburú sí, iru ẹda bẹ le ma ri alanu kankan tí yíò ran lọwọ.
Ìgbàgbọ yoruba nipé, igbin ki rin ko se alabapade alanu.
3. Ẹnití wọn ba fi igbin sa iṣẹ búburú sí, iru ẹda bẹ le nikan ma da gbe, ma da rin, ma da se gbogbo nkan.
Nitoripe igbin nikan ni o ma nda gbe inu ile, ikarahun ni ile igbin beni é ko le ba igbin meji ninu ikarahun kan.
JE KA GBA ADURA:
1. Gbogbo iṣẹ tó wù ki aiye fi igbin se lodi nitori mi, kobaje
2. Majẹmu ati agbara to fa ogun ifasẹhin ninu aiye mi, kobaje patapata
3. Ohun tí mo ṣe alabapade loju ala mi, to fa ogun sínu aiye mi, ni oju ala ati ojú aiye emi mimo e pin wa níyà amin
4. Eranko ni igbin jẹ, awa eniyan si ni Olorun fi se alakoso lori awọn eranko, gbogbo ohun ti aiye fi eranko se lòdì sí mi, e ma da'wọ iṣẹ duro ni agbaranla ti olohun
5. Iwọ igbin gbọ ọrọ Olorun, aiye ko gbọdọ lo iwọ igbin lodi si aiyé mi
AMIN AMIN AMIN
Call or WhatsApp me for any help on +2348162359840