04/09/2025
ADHD nínú ọmọdé
Àìlera Àìnífọkànsí Pẹ̀lú Ìṣe Àìṣedéédé (Attention Deficit Hyperactivity Disorder – ADHD) jẹ́ ààrun ìdàgbàsókè tí ọpọlọ, tí o maa ń se àkòbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wipé, a sábà maa n, so ó pọ̀ mọ́, ìwarapàpà (hyperactivity), ADHD ju àìní ìfarabalẹ̀ lọ. Àwọn ọmọ tí wọ́n ní ADHD lè ní ìṣòro Àìnífọkànsí nkan, àìní ìṣàkóso ara ẹni àti, ìhùwàsí wọn.
Níní òye àwọn àmi ADHD, àti kíkọ, bí a ṣe lè ran àwọn ọmọ tí wọ́n ní ADHD lọ́wọ́, jẹ́ ohun pàtàkì, fún àwọn òbí, àti àwọn tó ń tọ́jú wọn.
Àwọn àmì àìlera ADHD nínú àwọn ọmọ
ADHD, jẹ́ àìlera ìdàgbàsókè tí ọpọlọ, tí ó nííṣe pẹ̀lú àìnífọkànsì, àìfarabalẹ̀ àti ìwarapàpà. Àwọn àmì wọ̀nyí, lè fà á, kó ṣòro, fún àwọn ọmọ láti fara balẹ̀, sí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, àti láti tẹ̀lé ìtọná. Wọ́n lè ní ipa lórí, bí wọ́n ṣe ń kó ipa nípa ẹ̀kọ́, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti ìdàgbàsókè ìgbésí ayé wọn lapapọ̀.
Ó lè nira, làti mọ̀ pé ọmọ ní ADHD, nítorí pé, àwọn àmì rẹ̀, jọ ìhùwàsí tó wọ́pọ̀ láàrín àwọn ọmọ. Ṣùgbọ́n, àwọn àmì pàtàkì kan wà, tí ó lè jẹ́, kó hàn pé ọmọ náà ní ADHD:
• Aìfọkànsì (Poor attention) – Àwọn ọmọ tí wọ́n ní ADHD, máa n ní ìṣòro, láti fọkàn sí àwọn àlàyé kéékèèké, tẹ̀lé ìlànà, tàbí dúró lórí iṣẹ́ kan. Ó lè dà bí ẹni pé, wọ́n máa ń gbàgbé ǹkan, tàbí ki wọ́n máa pàdánù àwọn nǹkan lọ́pọ̀ ìgbà.
• Àìfarabalẹ̀ (Hyperactivity) – Ọmọ tí ó ní ADHD lè máa rìn kiri lójojúmọ́, won á máa gbòn tàbí sọ̀rọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Wọ́n lè ní ìṣòro láti jókòó ní ìdákẹ́jẹ, pàápàá jùlọ ní àyíká ìdákẹ́jẹ bí ilé ẹ̀kọ́.
• Ìwarapàpà (Impulsivity) – Àwọn ọmọ tí wọ́n ní ADHD lè ní ìṣòro láti dúró de àkókò wọn, won a máa dènà, dè àwọn elòmíràn, nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, tàbí, ṣe nǹkan láì ronú ṣáájú. Ìwà yì,í lè fa ìṣòro nílé, ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.
Àwọn àmì wọ̀nyí lè f'ara hàn, ju arawọn lọ, wọ́n sì lè hàn kedere ní àwọn àyíká kan pàtó, bí ilé ẹ̀kọ́, níbi tí ìlànà tó múnádóko, àti ìfọkànsìn tí ṣe pàtàkì.
Àwọn ìmọ̀ràn fún òbí nípa bí a ṣe lè tọ́jú àwọn ọmọ tí wọ́n ní ADHD
Àtìlẹ́yìn, fún ọmọ tí ó ní ADHD nílò sùúrù àti ìmòye. wọn ìmọ̀ràn tó wulo yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ọmọ rẹ:
• Ṣẹda àyíká tó dá lórí ìlànà (Create a structured environment) – Ṣíṣètò àkókò àti ìlànà tó dájú, máa ń ran àwọn ọmọ, tí ó ní ADHD lọ́wọ́, láti ní ìmọ̀lára ààbò, àti láti lóye ohun, tí a ń retí lọ́dọ̀ wọn.
• Pín àwọn iṣẹ́, sí ìgbésẹ̀ kéékèèké (Break tasks into smaller steps) – Ìṣẹ́ ńlá, lè dá ọmọ, tí ó ní ADHD lóró. Pín iṣẹ́ ilé tàbí iṣẹ́ ìlànà, sí ìgbésẹ̀ kéékèèké tí wọ́n lè ṣàkóso, kí o sì máa fún wọn ní ìwúrí, àti ìyìn lọ́pọ̀ ìgbà.
• Dín ìdènà kù (Limit distractions) – Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́, láti fọkànsí iṣẹ́ nipa, díndín àwọn nǹkan, tó lè yọọ lẹ́nu kù. Ṣẹ̀dá àyíká tó dákẹ́jẹ, tí ó sì dá lórí ìlànà, fún iṣẹ́ ilé, tàbí àwọn iṣẹ́ míì, tó nílò ìfọkànsì.
• Jẹ́ kí wọ́n máa ṣe eré ìdárayá (Encourage Physical Activity) – ṣíṣe eré Ìdárayá déédéé, lè ran ọmọ tí ó ní ADHD lọ́wọ́, láti ní agbára ìfọkànsì, àti láti mú ìfọkànsì wọn dára síi. Gbà wọ́n níyànjú, láti ṣe eré ìdárayá bíi, ijó, tàbí eré ìta gbangba.
• Ní sùúrù àti ìfaradà (Be Patient and Flexible) – Àwọn ọmọ tí ó ní ADHD, lè gba àkókò púpọ̀, láti parí iṣẹ́, tàbí kí wọ́n nílò, ìtọ́sọ́nà lọ́pọ̀ ìgbà. Máa ní sùúrù, kí o sì fi ìmòye hàn, nígbà tí wọ́n bá ní ìṣòro.
ADHD nínú àwọn ọmọ, jẹ́ àìlera tí ó wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí a sábà, máa ń sì ìtúnmò rẹ̀, ní òpò ìgbà. Nípa dídá, àwọn àmì rẹ̀ mọ̀ lákòókò, ṣíṣẹ̀dá àyíká tó ní àtìlẹ́yìn, àti lílo ọ̀nà tó múná dóko, àwọn òbí lè ràn, àwọn ọmọ wọn tí ó ní ADHD lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.
Ẹ máa rántí pé, gbogbo ọmọ ni ó yàtò, àti wípé, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn tó péye, àwọn ọmọ tí ó ní ADHD lè, ní ìgbésí ayé tó ní àṣeyọrí.