
22/07/2025
OSHOLE JENRAYEWA
================
●Eja Abori Ako & Abo
●Ewe Iyalode Pupa
●Ewe Iyalode Funfun
●Igba Oni Koko
●Miss Paris
●Oti Awon Agba 1
●Ose Dudu
OSHOLE je Ona Igbiyanju lati laa ninu Aye, Opo inu ile ni oti daru latara Aikosi Owo (Money), Beena ni Opo Igbeyawo ni Oti Tuka latara Aikosi owo, Opo Oko (Husband) ni o tidi Eni ti kole pase mo ninu Ile mo.Orisirisi omo ni Eto Eko won ti Taku si ona Nipase Aikosi Owo, Elomiran sa kuro ni ilu ti won ti bi, ti o si Kori lo si ilu miran Lati lo gbiyanju oro aje, Sugbon sibesibe Pabo ni Gbogbo re njasi.
Opo ni o pate oja kale ti won o bawon na, eyi je ki o yewa pe, Owo (Money) Je okan pataki ti a fi nri Aye se Leyin Alaafia ati Ifokanbale.
Opolopo ni o ni Awon Oluranlowo ti o le yo won kuro ninu Ise Ohun Iya (Poverty) ni egbe, sugbon ti won ko se Iranlowo fun won, Elomiran ni Egbon tabi Aburo, ti Eledumare segi ola fun won, ti won le yo won kuro ninu ise (Poverty) sugbon ti won o ya si won rara.
Owe Yoruba sope:
"Ajumobi o kan T'aanu"
Bi ao bari Eni feyin ti, Bi ole laari😒
Lododo! O kiise Ole (Lazy), sugbon kobadara ki
Owo (Money) ni nfuni ni Ifokanbale, Owo lonni di Alase nibi Gbogbo,Owo ni funi layo ati Idunu, Owo ni a fi nsoko Obinrin ninu ile, Owo ni a fi ndi Eni Giga.
Mobe Olohun Oba Ti o ni Buruji lodo, ki o tari Buruji si Gbogbo wa o 🙏🙏🙏
BI AOSESE
Ao pa Eja Abori mejeji yi, ao da Aya won dele ninu Ape Ijogun, ao to owo ti o ba wuwa meta lelori, ao ko Ewe Iyalode mejeji lelori, ao fi Odidi atare kan si, ao jo Gbogbo re papo, ao pin Ise yi si Ona meji, ao po okan mo Ose dudu, ao wafi lofinda Miss Paris yi po, ao ni fi Omi kankan si ose yi o, Ao ko sinu Igba Onikoko na.
Ao da Ekeji sinu Oti na, ao ju Owo odidi kan sinu re .
LILO RE
Ao ma we Ose yi ni Ojojumo pelu Adura pe:
"OBA TONI OWO, WATARI OWO SI ODO MI O"
Ao mamu Oti na ti a bati we ose na tan pelu gbolohun re pe:
"OTI KII TI,OTI KII TEE, KINMASE TI, KIMMASE TE".
"OMI KII TI, OMI KII TE, KINMASE TI, KINMASE TE".
Pelu ogo olohun oba ti o seda Ewe Ati Egbo Ti o ba nlo ise yi, Aje o ma wa o kiri ni.
Oba ti o ni Aje lodo, ki o tari Aje si Gbogbo wa🙏
Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880