Yorùbá ÀTÀTÀ

Yorùbá ÀTÀTÀ Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Yorùbá ÀTÀTÀ, Astrologist & Psychic, Columbus, OH.

06/12/2023

Ẹ dákun ẹ bá wa parí òwe yìí
👇🏼
Àtikékeré ṣẹrú...

12/30/2022

30 /12/2022
AYÉ TI DI OJÚ KEJÌ
Ìjàpá dé ilé àna rẹ̀ tán, o ní ìtọ̀ n gbọn òun.
Nígbà ti ìjàpá tọ̀ tán, o kọjú sí ìyá ìyàwó rẹ̀, o n de okùn ṣòkòtò rẹ̀.
Ìyá ìyàwó ìjàpá kígbe mọ́-ọ́n, ó ni "irú àrífin wo ní yìí, ṣé mo jẹ́ bí ìyàwó rẹ ni". Ijàpá dá àná rẹ lóhùn, o ni, "mo rò wípé ohun tí ọmọ rẹ̀ máa n jẹ nílé mi, wu ìwọ ìyá rẹ̀ jíjẹ ni". Ana ìjàpá dáhùn, ó ní, Ọlọrun kò níí jẹ́kí, oun ó jẹ ìjẹkúújẹ.
Ṣùgbón, ayé tí di ojú keji.
Àìsàn tó yẹ k'áráyé ó pè ní iké, ẹ̀tẹ̀ ni wọ́n n pèé. Àìsàn tó mú ẹ̀yìn enìyàn, tó tẹ̀ẹ́ wọ̀rọ̀kọ̀, tó tún wú kọngbẹ, ṣèbí òhun ló yẹ k'áráyé máa pè ní ẹ̀tẹ̀. Ṣùgbọ́n iké ni won n pèé.
Àìsàn tó mú ọmọ ìka ọwọ́, àti ẹsẹ̀ ènìyàn, tó gée kéé,kèè,kéé, ṣèbí, òhun ló yẹ k'áráyé máa pè ní iké, ṣùgbọ́n ètẹ̀, ni wọ́n n pèé.
Ayé tí di ojú kejì.
Bàbá n fún ọmọ rẹ̀ lóyún. Ìyá n bí ọmọ fún ọmọ bíbí inú rẹ̀.
T’ẹ̀gbọ́n, t’àbúrò n fẹ ará wọn .
Ọkùnrin at'ọkùnrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ n fẹ́ ará wọ́n.
Obìnrin àt'obinrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, n ṣe ìyàwó. Ayé tí di ojú Kejì.

Bí ọdún ṣe n lọ s'ópin, orí rẹ kò níí gbàbọ̀dè ikú. Ayọ àti àlàáfíà ló máa fí wọ inú ọdún tuntun lasẹ Èdùmàrè.
Wòlíì Fágbọrọ̀ Emmanuel ló n kí wa pé a kú ojúmọ́.
Èdè Yorùbá kò gbọdọ̀ parun.
08033868462.

Àmí, Àmí, Àmí lórúkọ Jésù
11/13/2022

Àmí, Àmí, Àmí lórúkọ Jésù

Ipò tí ẹnikẹ́ni kò dé rí ní ìran Jósẹ́fù, Ọlọ́run mú Jósẹ́fù dé ibẹ̀.

Ipò ọlá tí yóò mú ògo bá orúkọ Olúwa, àánú Ọlọ́run yóò gbé ọ dé ibẹ̀ lórúkọ Jésù.

Ìwúre fún oṣù ọ̀wàwà, ẹ gbìyànjú láti wò ó
10/02/2022

Ìwúre fún oṣù ọ̀wàwà, ẹ gbìyànjú láti wò ó

Ìwúre fún oṣù ọ̀wàwà (prayers for the month of October, 2022)

09/21/2022

Bí a ṣe ń jáde lọ lónìí ọjọ́ Àánú, àánú Ọlọ́run yóò fọhùn fún wa ní ibi gbogbo láṣẹ Èdùmàrè

Bí o ṣe ń lọ nínú ìrìnàjò ọ̀sẹ̀ yìí, máa rántí pé:Ilé kan kò kun ara rẹ̀ lẹ́fun, ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan kò ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, fú...
07/24/2022

Bí o ṣe ń lọ nínú ìrìnàjò ọ̀sẹ̀ yìí, máa rántí pé:

Ilé kan kò kun ara rẹ̀ lẹ́fun, ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan kò ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, fúnra olówó ẹṣin ní í tún ẹṣin ṣe. Tọ́jú ìwà rẹ.

06/23/2022

23/6/2022
Olóngbò tó bá ní àròjinlẹ̀, kò níí pa aboyún èkúté jẹ.

Ọkùnrin tó bá ṣú ìyàwó bàbá rẹ̀ lópó, kò lè mọ iyì àna

Ewúrẹ tó jí abọ́ èlùbọ́ kan jẹ nílé olówó rẹ̀, ó ti j’oúnjẹ ọdún mẹ́rin mọ́-ọn

Akúwárápá ló n ṣ’ọdún itọ́. Atọ̀ọ́lé ló n ṣ’ọdún ìtọ̀.

Lákíríboto ló le ṣ’ọ̀rẹ́ òkóbó.

Igi tí yíó ṣe bí ọ̀pẹ kò níí l’épo lórí.

Ọba n d’ádé, orúùrù n d’ádé, tani yíó d’ádé orúùrù bikòṣe adé ọba. Adé ọba ló yẹni, yatọ sí adé orúùrù.

Ìmàdò kìí mumi lódò, k’ómi odò náà o tòrò.

Ọlọrun kò níí da ọnà rẹ rú. Oníṣẹ́ ikú kò níí jẹ fún ọ. O kò níí rógun ìjakulẹ̀ lasẹ Èdùmàrè.
Wòlíì Fágbọrọ̀ ló n kí wa kú ojúmọ́.
Èdè Yorùbá kò gbọdọ̀ parun.

03/04/2022
01/29/2022

́_gbẹ́nàgbẹ́nà ni ilẹ̀ Yorùbá, iṣẹ́ pàtàkì ni iṣẹ́ yìí jẹ́ nínú iṣẹ́ àárọ̀ Yorùbá. Iṣẹ́ ìran ni. Ṣùgbọ́n ààyè wà fún kíkọ́. Ọmọ ọ̀gbẹ́nà lówó ni ìdílé yìí jẹ́ láti àárọ̀ ọjọ́ ayé wọn. Kò sí àrà tí wọn kò le fi igi dá bí ọwọ́ wọ́n bá tẹ igi. Àwọn ìran yìí ti wà ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó dé ilẹ̀ ẹ wa. Díẹ̀ nínú orúkọ ìdíle yìí ni: Ọnàbánjọ, Ọnàníyì, Ọnàkúnlé, Ọnàwùmí, Ọnàkẹ́mi. Abbl.

Díẹ̀ lára iṣẹ́ wọn nìwọ̀nyí: ààsẹ̀ ìyẹn ìlẹ̀kùn ńlá, òpó ilé ẹlẹ́wà, ère, odó, ọpọ́n, orógùn, ìgbakọ, ẹ̀rúkọ́, ọkọ̀ ọlọ́pọ́n ojú omi. abbl.
Oríkì wọn ni:

"Ajíbọ́nà ọmọ Ajíbogúndé
Àrè-Ọ̀jẹ́ Ọlọ́jọwọ̀n.
Làgbàyí ará àgbóṣòkun
Ọmọ agbẹ́gi rébété ṣe láyaba.
Àrè pagi dà, sọgi dèèyàn!
Ọ̀tún mi ìgbẹ́gi,
Òsì mi ìṣọ̀nà.
Àrè_Ọ̀jẹ́ ọmọ a-pà-rókò-lówó-lọ́wọ́.
Ìṣẹ́pẹ́ orí ìròkó owó ni.
Ìtì tí ń bẹ lára ìrókò, owó ni.
Kújẹ́nrá ará Àgbóṣokun.
Làgbàyí mo gbẹ́nà n ò lówó lọ́wọ́
Mo yá a gbẹ́pọ́n ire fáyaba.
Làgbàyí ọmọ afẹ̀dùn wọ́gi nífun dà sílẹ̀.

Ọmọ a dagí lẹ́kun èso,
Ọmọ apòòrì kági àdùgbó
Ọjọ́ tí Làgbàyí n toko ọnà á bọ́,
Gbogbo igi oko ló ń sáré ikú yẹ́tuyẹ́tu.
Apá ń sáré, ìròkó ń sá.
Ọmọ abu-kẹ́kẹ́ igi lẹ́wọrọ lẹ́wọrọ,
Ọmọ abàbàjà igi pẹ̀ẹ̀tò pẹ̀ẹ̀tò!"

© Prince Adefemi Ayanwale Ghaabio
Ọkọ Àbẹ̀ó Ọlọ́mú oyin.

Iṣẹ́ mẹ́ta ni kò tó ọmọrí odó ṣeTó bá fojú gúnyánA fẹ̀yìn gún ẹ̀lúA fagbedeméjì tìlẹ̀kùn daindainLó díá fún ìbàlẹ̀ àyàTí...
01/02/2022

Iṣẹ́ mẹ́ta ni kò tó ọmọrí odó ṣe
Tó bá fojú gúnyán
A fẹ̀yìn gún ẹ̀lú
A fagbedeméjì tìlẹ̀kùn daindain
Ló díá fún ìbàlẹ̀ àyà
Tí ń lọ rèé ra ìsinmi lẹ́rú
Ìbàlẹ̀ àyà
Àwa dé ibi tó tutù
Ẹ jẹ́ ká sinmi.

Nínú ìrìnàjò ọdún 2022 yìí, gbogbo ẹ̀yin olólùfẹ́ Yorùbá ÀTÀTÀ,
Ẹ ó ní ìsinmi
Ọkàn yín á balẹ̀
Ìdààmú kò ní í jẹ́ ìpín yín láṣẹ Èdùmàrè.

Bí Olúwa ti ń bẹ àti bí ẹ̀mí rẹ̀ ṣe wà, ìbànújẹ́ òpin ọdún kò ní í jẹ́ ìpín rẹ láṣẹ Èdùmàrè.
12/17/2021

Bí Olúwa ti ń bẹ àti bí ẹ̀mí rẹ̀ ṣe wà, ìbànújẹ́ òpin ọdún kò ní í jẹ́ ìpín rẹ láṣẹ Èdùmàrè.

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́RÚA kì í bínú owó ká da owó síná,Ọmọ aráyé kò ní í bínú àwaA kì í bínú fi ẹyin adìẹ sọ̀kòAráyé kò ní í ...
12/08/2021

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́RÚ

A kì í bínú owó ká da owó síná,
Ọmọ aráyé kò ní í bínú àwa
A kì í bínú fi ẹyin adìẹ sọ̀kò
Aráyé kò ní í bínú àwa
Ọ̀tọ̀ọ̀kùlú kì í bínú aásà kí wọ́n má fín in

Bí gbogbo wa ṣe ń jáde lọ lónìí ọjọ́ àánú, ìyọ́nú ayé ni ká rí, a kò ní í rí ìbínú ayé láṣẹ Èdùmàrè. Ire o!

© Ààrẹ Òjó Philip Òkunlọlá 8/12/2021

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀Bí a ṣe ń jáde lọ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gunÒré lóní kí ire máa ré mọ́ waỌ̀yà ló ní kí ire ó yà lọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan w...
12/07/2021

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀

Bí a ṣe ń jáde lọ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun
Òré lóní kí ire máa ré mọ́ wa
Ọ̀yà ló ní kí ire ó yà lọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ló ní kí gbogbo wa pátá rí ire gbà
Àlọ wa yóò dára, àbọ̀ wa náà yóò sì dára láṣẹ Èdùmàrè. Ire o!

© Ààrẹ Òjó Philip Òkunlọlá

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́ AJÉÒkun kì í ráre omiẸ kò ní í ráre owó Ọ̀sà kì í ráre odòẸ kò ní í rare owóOjoojúmọ́ layé ń ta èṣù lọ...
12/06/2021

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́ AJÉ

Òkun kì í ráre omi
Ẹ kò ní í ráre owó
Ọ̀sà kì í ráre odò
Ẹ kò ní í rare owó
Ojoojúmọ́ layé ń ta èṣù lọ́rẹ
Ojú kì í pọ́n èékánná ọwọ́ dalẹ́

Bí ẹ ṣe ń jáde lọ lónìí, àtọkùnrin, àtobìnrin, ọmọdé àti àgbàlagbà, onílé àti àlejò ni kí wọn máa ta yín lọ́rẹ ohun rere láṣẹ Èdùmàrè. Ire o!

© Ààrẹ Òjó Philip Òkunlọlá 06122021

Gbogbo ohun rere tí ọkàn ń fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ṣùgbọ́n tí kò tí ì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, bí ọdún yìí ti ń lọ sí ìparí, Ọlọ...
12/05/2021

Gbogbo ohun rere tí ọkàn ń fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ṣùgbọ́n tí kò tí ì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, bí ọdún yìí ti ń lọ sí ìparí, Ọlọ́run yóò fi àánú yọ̀ǹda rẹ̀ fún ọ láṣẹ Èdùmàrè.

12/04/2021

Ó wu ewé gbogbo kó fà kálẹ̀, ó wù Olódùmarè ló fààyè gba gbọ̀ọ̀rọ̀ kó fà kálẹ̀ ju gbogbo wọn lọ.

12/02/2021

ÀROKÒ ÌKÉDE

Púpọ̀ àrokò ló wà ní abẹ́ ìsọ̀rí yìí. Ìkéde tí à ń wí níbí yìí kì í ṣe pé kí á gbé agogo máa kígbe kiri tàbí kí á pe gbogbo ìlú jọ kí á tó fi àrokò jíṣẹ́. Ṣùgbọ́n ohun tí irúfẹ́ àrokò wọ̀nyí máa ń ṣe ni láti fún wa ní ìròyìn kan pàtó nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

1. Fífi ahá ọlọ́mọrí tí a kó nǹkan èlò díẹ̀ sí, tí a wá fi ránṣẹ́ sí ọkùnrin tí ó wà lẹ́yìn odi (àwọn nǹkan èlò yìí lè jẹ́ ìrépé aṣọ, àkúfọ́ àwo àti ẹ̀rúnrún ẹní)

Ìtúmọ̀ èyí ni pé ìyàwó rẹ̀ ti kó gbogbo ẹrù kúrò nínú ilé.

11/19/2021

ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́ ẸTÌ

Ẹ kò ní í bínú tí ń túlé

Ẹ kò ní í ní sùúrù tí ń pa ènìyàn

Ohun tí ọmọ aráyé kò fi pamọ́ sí i yín lọ́wọ́, wọn kò ní í béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín láṣẹ Èdùmàrè.

© Ààrẹ Òjó Philip Òkunlọlá 19/11/2021.

Address

Columbus, OH

Telephone

+2348038285032

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Yorùbá ÀTÀTÀ posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Practice

Send a message to Yorùbá ÀTÀTÀ:

Share

Share on Facebook Share on Twitter Share on LinkedIn
Share on Pinterest Share on Reddit Share via Email
Share on WhatsApp Share on Instagram Share on Telegram