30/06/2023
Ọdún ọmọ Ejio, Ayọ̀ ọmọ Ọbàlọràn, Àkànnàmọ̀gbò kìí pọdún jẹ,
Emi Ọlálékan aa pẹ́ láyé bí ewé àpẹ́, Pípẹ́ ni ti pẹ́pẹ́ nígbó, Pípẹ́ ni bàtà ń pẹ́ lẹ́sẹ̀ pẹ́pẹ́yẹ, Kánrinkéṣe ni Èṣù ń pẹ́ lójú òde,
Ọ̀pọ́n kò ní sé kankan
Òkùtẹ̀ kò ní yẹ̀ bọ̀rọ̀bọ̀rọ̀
Omi agbada kò ní dànù wàràwàrà
Asodun modun niisawo a*odun modun,
Asosu mosu níí ṣawo a*osu mosu,
Ọdọọdún láárí orógbó
Ọdọọdún láárí awùsá,
Ọdọọdún láárí ọmọ obi lórí àtẹ
Ọdọọdún ni s'apo nruwe
Ọdọọdún ni peregun ni láṣọ ma*o
Igúnnugún kii kuu l'ewe ma kasai d'arugbo
Akalamagbo kii podun jẹ mio nii pàá odun jẹ
Ayi gbirikaye lorukọ ti a npè ifa, oke namonamo lórúko ti a npe Esu òdàrà, abule ma tètè kú loruko ti a npe òrìsà nlá, esekan ofun kii bawon ku iku ọwọwọọ !
Ọlálékan , mi'o ni b'awọn ku iku ọwọwọọ lasẹ elédùmarè!!
Ẹkun ni kànakana n sun wogbo
Ako alangba Kiise erun méjì ,
Ewe iṣu kii pé rẹ danu
Ewe àgbàdo kiise erun méjì,
Ẹnikẹni toba perí mi laida kòó rẹ danu !
Ẹnikẹni toba dojú aburu kọ emi Ọmọ ADEPOJU ki oun burúkú o ṣẹlẹ sí tayatomo !
Wọn ránmi lọ sigbo eerin mo dèé,
Wọn ránmi lọ sọdọ oriṣa mo bọ,
Won ni mo fe iyawo ògbóni, mo ni mio fe iyawo ògbóni,
Won ni mo sọrọ imule lẹyìn, moni mio sọrọ imule lẹyìn,
Aseyin wa aseyin bo, won kẹbọ kóògùn timi..
Ẹni tó kẹbọ, at'ẹni too kóògùn timi,
A kuu dojude ni ahun nkú,
A kuu dojude ni igbín nkú ,
Ọjọ ti adiẹ òpìpì bá sọrọ ilẹ, ọjọ náà níí deran ilẹ.
Gbogbo awọn ọta emi BABA ỌGBỌN AWON AGBA won yíò dé ẹran ilẹ !
OGORUN ODUN LÓNI, AWA WON NI !
Idi meji bami di iku mode ko bami di Arun mode..
Eka ko ka iku, ofo ati Arun danu lo rimi,
oyeku Koma bami yeku danu lojo gbogbo, Ejiogbe Koma gbemi bori gbogbo ota,
Nitori ki Apa aiye Makami, aiye doyi ka Apa, Apa okapa, won Doyika ose apa oka ose,
won Doyika ona Apa oka ona...
Bomode ba dariso Apa, Apa Apa,
Bomode ba dariso iroko iroko ako wo,
ojo tomode tagba badariso oruru niwon nru oku re bo wale,
ojo aba fagbo foro loro ngba,
ojo aba faja fogun labe,
bogede ba nawo ija ara re lofi nlu,
ki gbogbo ota mi ma fowo ara won se arawon, ki emi ma gbe igbe aiye se rere,
biwon ba pemi lorun kinma je,
biwon ba pemi nipe odi kinma je,
nitori ese kan ofu kiiba Egbe re lo sale de orun,
edan kii ku, edan kii run, atojo aterun koko ko lara edan nle !
OJOJUMỌ LARA MI O MA LEE !
HAPPY BIRTHDAY TO ME !
PROF. ADEPOJU KAZEEM ỌLÁLÉKAN
(Ọmọ ọba mẹta )