
21/07/2025
*🌺ISE NI OGUN `SE*
*🖊️Mura si ise ore mi*
*🖊️Ise ni afi ndeni giga*
*🖊️Bi ako ba reni fehinti*
*🖊️Bi ole la a ri*
*🖊️Bi a ko ba reni gbekele*
*🖊️A tera mo ise eni*
*🖊️Iya re le lowo lowo*
*🖊️Baba re si le leshin le kan*
*🖊️Bi o ba gboju le won*
*🖊️Ohun te tan ni mo so fun o*
*🖊️Ohun ti a ko ba jiya fun*
*🖊️Se kii le tojo rara*
*🖊️Ohun ti a ba fara sise fun*
*🖊️Ni npe lowo eni*
*🖊️Apa lara*
*🖊️Igunpa ni iye kan*
*🖊️Bi aiye ba nfe o loni*
*🖊️Ti o balowo lowo*
*🖊️Aye a ma fe o lola*
*🖊️Jeki o wa ni ipo atata*
*🖊️Aiye a ma ye o si terin-terin*
*🖊️Jeki o deni ti rago*
*🖊️Ko o ri bi aiye ti nyinmu si o*
*🖊️Eko si le seni doga*
*🖊️Mura ki o ko dara-dara*
*🖊️Bi o ri opo eniyan*
*🖊️Ti n fi eko serin rin*
*🖊️Daku ma fara we won*
*🖊️Iya nbo fomo ti ko gbon*
*🖊️Ekun mbe fomo ti o nsa kiri*
*🖊️Ma fowuro sere ore mi*
*🖊️Mura si ise ojo nlo.*👌🏼