07/01/2026
ÀÁNÚ ATÍ SÁÀRÁ ṢIṢÉ
Kínní iyatọ tó wa láàrín Sára ṣíṣe ati Àánú ṣíṣe?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mań gbe síra wọn.
Ǹjẹ́ ìwọ ńṣe sára botiyẹ, Ǹjẹ́ oń ṣe àánú bí?
🤙 Ọpọlọpọ enìyàn mań sábà ró wípé nkankán náà ni Àánú àti Sáàrá ṣíṣe. Iyatọ wá nibẹ lọpọlọpọ.
Kòsí ẹsin tó tákọ ṣíṣe sáàrá tàbí àánú ṣiṣé. Ọna ti onikaluku gbá ṣàlàyé tìrẹ ló yatọ.
🤙 Àánú ṣíṣe sọrọ nípa kí éèyàn máṣe olurànlọ́wọ́ ọmọ lakéèjí pẹlu ọkàn kàn láì lérò láti gbá nkan padà lórí ẹ, eyí nígbà míràn á máà wá pẹ̀lú ìbéèrè fún iranlọwọ. Ó dará ki éèyàn má pesè fún ọmọ lakéjí boyá wọn béèrè tàbí wọn ko béèrè fún àánú lọwọ rẹ . Láti rí anfáàní àánú gbá lọdọ Ọlọ́run, Ó dará ki éèyàn ma fí ọkàn kán ṣe àánú nítorí tí éèyàn kòbá fì ọkàn kán ṣe àánú irú àánú bẹ kòní ìwúlò lọdọ Ọlọ́run Ọba bẹ́ẹ̀ kòsí anfáàni ninu ayé ẹni bẹ. Gbògbo iká ọwọ wá ko dọ́gba, bẹẹni kòsí ẹni ti kólè ṣe àánú, ṣùgbọ́n ó kọ jẹ́ wípé àní ojú àánú jù ará lọ. Ẹlòmíràn lé fi ẹyinjú rẹ ṣe àánú bẹ́ẹ̀ ẹlòmíì kólé fì nkan kékeré báyàn ṣeré. Kìí ṣe gbogbo éèyàn ló lójú àánú tàbí ló mọ àánú ṣe. Ẹlòmíràn tí éèyàn kòbá ti sọ gbogbo ọrọ ẹnu rẹ tán tàbí má kúlọ báyìí, ọkàn rẹ koti ṣí láti ṣe àánú fun ọmọ lakejí ti èyí kòsì dará. Elédùmarè fẹ kí ó márò rárá léméjì kí ó to ṣe àánú ọmọ lakéji. Bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run nifẹ Aláànú, ó sì dawá lọ́tọtọ láti lèmá ṣe fún ará wá. Ènìyàn kólé ní gbógbó nkan tán láyè, bẹ́ẹ̀ bí éèyàn ní nkan kólé nìí ni gbogbo igbá , ijọkán ni ijọkán tí yóò yọ́lẹ.
🤙 Ọlọrun tó dáwà, mọ wípé okè àti ìsalẹ̀ ni ilé ayé. Ó le ní lónìí , ko safẹrẹ diyẹ́ lọlá. Bẹ́ẹ̀ Ó lèwá ni ipò oké lónìí, ki ó walẹ̀ lọla ti ó sìmá nílò àánú láti goké padá. Ayé kó pin síbi kàn, ayé ń yilọ́ ní kó duró. Bí ó baṣé ṣe àánú si, loṣé ma rígbà lọdọ Ọba Okè . Kòsí ẹni tí kólé niló iranlọwọ torí Ọlọ́run dáwà láti maṣe olurànlọwọ́ ará waní. Kòsi sí ẹni toń ṣe àánú dáàdá ti kìí ri idágbá sókè nínú gbogbo adáwọlé rẹ́ nítorí Ọlọ́run Ọba nifẹ sí aláànú pupọ , bẹẹni àwọn ọmọ rẹ náà yóò marí gbà ní ọjọ iwájú. Ṣíṣe àánú jẹ́ ọnà tí á fín ṣètò silẹ ọjọ iwájú fún ibí tín án lọ lẹ́yìnwá lọlá.
🤙Nínú àwọn Irawọ, Àwọn Ọmọ Irawọ Omí loṣé àánú jù. Pupọ nínú àwọn onirawọ yi, adamọ wọn ní láti máṣe àánú fún ọmọ aráyé. Bi wọn bán ṣeṣé àánú sí, ni wọn yóò mari gbà nínú ayé wọn láti ọ́dọ Ọlọ́run Ọba Okè. Ọlọrun dá ọpọlọpọ wọn sáyé láti maṣé àánú ni, botiyẹ jẹ wípé àwọn éèyàn mań sábà fẹ fí ibí sú wọn. Wọn kó gbọdọ jẹki èyí bá ọkàn wọn jẹ láti tẹpa mọ àánú ṣíṣe nítorí àánú sisé yiní yóò má gbé wọn fó gbogbo iṣoró ayé àti ìdojúkọ bẹ́ẹ̀ tí óòré ayé wọn yóò ma kún si lái lérò.
🤙Àwọn Onirawọ Erupẹ gbọdọ kún fun àánú ṣíṣé, pupọ ninu wọn kìí lawọ bẹẹni ìṣoró àti ìdojúkọ sí pọ nínú ayé. Nínú líla ọwọ wọn ní wọn yóò tirí ọna abayọ láti tètè borí ìṣòro wọn. Èyí tó lawọ lọpọlọpọ nínú wọn mań sábà tètè borí óogún nítorí Ọlọ́run amá tètè gbéga bẹẹ ní bori ìṣòro rẹ kíákíá. Àǹfààní wá pupọ fún èyí to bá lawọ ninu wọn. Irawọ Erupẹ Fúnfún losí lawọ jù nínú àwọn àbudá Irawọ yi. Irawọ Erupẹ Erukú, pupọ nínú wọn fẹ́ràn láti ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn mójú owó lọpọlọpọ tí èyí á sì máa diná óòré àti iranlọwọ ayé wọn tí wọn nílò, wọn gbọdọ lawọ́ lọpọlọpọ láti rí àánú Ọlọ́run gbá fi borí ìdojúkọ ayé wọn lásìkò . Ìwọ tí ó jẹ Irawọ Erupẹ, bawó ló ṣe nṣé àánú sí.
🤙Irawọ Iná, Pupọ nínú àwọn onirawọ yí, Aláànú ni wọn jẹ agágá Iná Tongbonarírí àti Ina Atupá. Ṣùgbọ́n Àánú ṣíṣé láàrín Irawọ Iná Tokànyánrán kìí fibẹ wọpọ,Onirawọ yí gbọdọ lawọ́ torí ọpọlọpọ wọn mójú owó bẹ́ẹ̀ wá má ṣe iyè méjì láti ṣe àánú tí eyí kò dára fún ìpín Irawọ wọn. Eyí tóbá kún fún àánú ṣíṣe ninu wọn , á má tètè di éèyàn nlá láyè nítorí àánú ná yóò máa ṣe àtilẹ́yìn Iná wọn dádá láti gbá agbára fi borí ìdojúkọ ayé wọn. Nítorí idí èyí kí ọpọlọpọ onirawọ yí tẹpa mọ àánú ṣíṣe láì ṣe iyè méjì láti tètè gbé wọn débi gíga wọn láyé.
🤙Ó dará ki éèyàn maṣé àánú lọpọlọpọ, kìí ṣe kí éèyàn tó béèrè lọwọ rẹ fún nkan kí ó tó ṣe, ànfààní pupọ wá nínú ki éèyàn ṣe àánú fún àwọn éèyàn kí wọn to béèrè bẹẹni kìí ṣe kí éèyàn toní owó pupọ lọwọ tàbí ni nkan rẹpẹtẹ kí ó tó bẹ́rẹ́ sini ṣe àánú fún àwọn éèyàn. Kódà àsikò àìní yẹn gángán ni Ọlọ́run fẹ kí éèyàn kún fún àánú ọmọlakeji jù . Ọlọ́run á má fi àsìkò yí dán ìgbàgbọ́ ènìyàn wò nítorí àti kékeré báyìí ni yóò tirí bí ènìyàn ṣelè ṣé óòré tó ní ilé ayé. Kòsí nkan ọ́fẹ́ láyé, Bi ó bán béèrè nkan pàtàkí lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba, báwo ni àánú rẹ ní ṣiṣe ṣé pọsi nítorí Ọlọ́run nifẹ aláànú ẹ̀dá dáàdá.
🤙Ẹlòmíràn kìí lẹmi ati ṣe àánú, Ẹlòmíì kìí lé ṣe àánú láì má gbá nkan padà, èyí kìí ṣe àánú rárá, bẹẹni ẹlòmíì ń dúró dìgbá ti Ọlọrun bá gbé òun didé kí òun tolè máṣe àánú ti èyí sìn dìná óòré àti didẹ́ mọ, yóò wà róbi wípé ayé loń ṣe òun tí kosi ribẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí jabọ́ láti ipò oké nítorí aìmalé ṣe àánú, pupọ ti dí olowó aná nítorí wọn kìí lé ṣe ìtọrẹ àánú nígbà tí wọn débi gíga láyé.
🤙 Àánú dára lọpọlọpọ fún wá, Àǹfààní pupọ wá nínú àánú ṣíṣe. Kìí ṣe owó nìkan lá fìn ṣàánú. Àwọn nkań bí Owó, Aṣọ, Omí, Gbigbáni ní ìmọràn gìdí, dí duró tiní lásìkò ipọnju , ṣíṣe atọna ọmọ lakejí, ríran ọmọ lakejí lọ́wọ́, Fífi ìfẹ́ hàn si éèyàn tọ́kantọ́kan, Lílò inukán pẹ̀lú ọmọlakéji , gbígbà ẹni ni ìyànjú toni anfáàni sínú ayé wọn , dídá sí nkan ti yóò ṣe ọpọlọpọ éèyàn láǹfáàní tó dará, tútùn nkan ará wa àti ọmọlakéjì wáṣe àti bebelọ.
🤙Àwọn ọ̀nà ti àlè gbá máṣe àánú fún ará wá pọ lọpọlọpọ. Ọlọrun nifẹ si áláànú, aláànú éèyàn kìí jìyà ọ́lọ́jọ́ pipẹ, áláànú amá rí igbégá àti ìlọsíwájú dáàdá ninu ayé rẹ lọpọlọpọ . Aláànú amá ri óòré láyé bẹẹni ni Lọrún ni ọjọ ìkẹyìn, orúkọ aláànú éèyàn kìí parẹ́ layé. Gbogbo àánú ti ó ban ṣe, orí wá laṣé fún torí gbogbo ànfáàní ibẹ́ àwa àti ọmọmọ́ wá ní yóò jẹ anfáàní fún ní ọjọ ọlá . Ìwọ tí ó kin ṣé àánú, báwò ní ètò ikẹyìn ayé rẹ . Lojumọ kan, ó dárá láti ṣe àánú, àánú ọjọ kàn amá fá óòré ọlọjọ́ pipẹ́ sinú ayé ẹni.
🤙Lápá kejì, Sáàrá Ṣíṣe jẹ Òun tí ó dára fún wá láti máṣe lọpọlọpọ fún anfáàní àti àtilẹ́yìn gbogbo adúrà atí igbinyanju ayé wá láti tètè gbé ayé wa ní irọrun. Ó dará láti ṣe sáàrá, kí ilé ayé wa lé malọ́ ni irọrun botiyẹ, Sáàrá gbọdọ má tẹle àwọn etò àdúrà wá sí Ọlọ́run Ọba Oké ki gbogbo òun ti ań fẹ́ bẹ béèrè le tete wásí ìmúṣẹ nínú ayé wa, bẹ́ẹ̀ kí gbògbò ìṣòro àti ìdojúkọ ayé wa léwa sópin ní kíákíá. Sáàrá ṣíṣe wá láàrin iwọ́ àti Ọlọ́run Ọba tó dawá. Ọlọrun ti dá àwọn Jámánì kàn sí ilé ayé onikálukú láti má gbọhun àwọn adúrà wá bẹ́ẹ̀ sáàrá tó tẹle ní àwọn ọjọ oriré gbogbo ipin Irawọ kankán. Gbògbo ẹdá tó wá sáyé ni yóò fojú ri ìdojúkọ kán sí òmíràn ṣùgbọ́n Sáàrá ṣíṣe fún wá jẹ ará nkan ti á fiń tètè rán tẹle gbogbo àdúrà àti igbinyanju wá sí iwájú Ọlọ́run Ọba to dawá ki alé tètè ri iyatọ tó peyé ninu ayé wá. Gbogbo Ìpín Irawọ lóní sáàrá ṣíṣe atí ọjọ́ to dará fún wọn láti máṣe Sáàrá. Sáàrá gbọdọ má bá àwọn éèto wá lọ , bóyá éèto adurà, awẹ tàbí igbinyanju. Lẹ́yìn àwọn nkan éèto yí, Ó dára kí sáàrá ṣíṣe tẹ̀lé kí àlè tètè rí esí àwọn nkan wọn yi ní kíákíá pẹlu Agbárá Ọlọ́run Ọba.
🤙Sáàrá Ṣíṣe amá ṣínà fún wá kíákíá, kósì nkan ọfẹ layé yí, kódà gbogbo óòre tí Ọlọ́run ọba ṣe fún wá , ágbọ́dọ̀ ṣe idúpẹ láti lé marí óòré míràn gbá. Torí ẹrú to bán dúpẹ́ yóò rí óòré mi gbá kiákiá botiyẹ, bẹẹni sáàrá ṣíṣe jẹ́ lọdọ Ọlọrun. Ọlọ́run Ọba ti ṣe àwọn éèto sáàrá fún wá láti má ṣe lorèkorè láti lè marí àánú àti ojúreré òun gbà kiákiá nínú ayé wá ju awọn ẹlẹgbẹ wá lọ . Ọpọlọpọ éèyàn lèmá ṣé àánú ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo éèyàn lón ṣé sáàrá. Sáàrá wúlò gan nínú ayé ẹ̀dá Èniyàn, kìí ṣe nígbà tí ìṣoró àti ìdojúkọ badé nikán lóyẹ ki amá ṣe Sáàrá. Bi àánú ṣe pọn dańdań tó nọni sáàrá ṣíṣe náà ṣe kókó ninu ayé ẹda ènìyàn fún ìlọsíwajú to péye ninu ayé wá . Ó dára lọpọlọpọ kì á mú sára ṣíṣe lópópódun, kí Irawọ àti ògo wá lé tètè tán layé botiyẹ bẹẹni láti ṣí ọna gbogbo idènà àti ìdojúkọ wá ní kiákiá.
🤙Ẹlòmíràn sáàrá ṣíṣe nikán ni óògùn oriré rẹ láti borí gbogbo ìṣòro ayé rẹ ṣùgbọ́n kìí ṣe botiyẹ, òun lón jẹki irú ẹni bẹ má jìyà lasán layé tí koyẹ́ . A tún mań ṣe sára lorekore láti fí túù àwọn ẹlẹgbẹ ọ́ọ̀rún wá, eyí fún àwọn ọmọ ẹlẹgbẹ. Oríṣiríṣi ẹgbẹ́ lowá bẹẹni òun ti wọn fín túù wọn àti ọna tí wọn gbá tú wọn yatọ sirá wọn, bí awọn ọmọ ẹlẹgbẹ bátin ṣe Sáàrá fun àwọn ẹlẹgbẹ ọ́ọ̀rún wọn lorekore ni àwọn náà yóò ma tarí óòre gidigan sínú ayé wọn tí ìyípadà atí ilọswájú gidi yóò sìmá debá ayé wọn ní kiákiá.
🤙 A tún mań ṣe sáàrá fún àwọn okú ọ́ọ̀rún wá, láti fi tẹ́lẹ̀ ìgbé ayé wọn ní ajolé ọ́ọ̀rún fún wọn bẹẹni fiṣé irantí wọn tí yóò jẹ ànfáàní nínú ayé tiwà náà torí ẹni tó bán ṣé Sáàrá fún okú ọ́ọ̀rún rẹ, yóò marí àtilẹ́yìn okú ọ́ọ̀rún wọn láti borí ìṣoro atí ìdojúkọ ayé wọn kiákiá. Ó dará ki amá ṣe sáàrá fún àwọn arugbó wá tàbí òkú ọ́run wá. Tí á bań ṣeyí, wọn yóò má ṣe alátilẹ̀yìn wá nínú gbògbo oun tí á ban ṣé layé.
🤙Á tun lé ṣe Sáàrá láti fi ré àlá burúkú lórí wá bẹ́ẹ̀ láti ṣiná àlá réré lórí ayé wá kiákiá. Nígbà mì tí á ban lá àwọn àlá ti ko dará to lorí ayé wá , sáàrá ṣíṣe amá báni ṣe olutọ́nà si irú àlá bẹ ki ó ma balé ṣe lorí ayé wá bẹẹni tí á ba lá àwọn àlá gidi náà , Ó dara lati ṣe àdúrà atí sáàrá lorí ẹ kí olè tètè wásí imúṣẹ ninú ayé wa lásìkò .
Sáàrá ṣiṣé tún dará lorí atúnṣé Irawọ wá, tí éèyàn bati fẹ Irú Irawọ ti kobá Irawọ tirẹ mú ti èyí sítì fà aìnilọ́siwajú sinú ayé irú ẹni bẹ, ó dára kí ẹni náà gbọnjú tàbí tẹpá mọ Adúrà ati Sáàrá ṣiṣe láti fí bẹ Ọlọ́run Ọba fún atúnṣe lorí Irawọ wọn, kí irú ẹni bẹ lé tètè rí òun réré ti ó rán mọ Irawọ wọn bẹ́ẹ̀ kí ìlọsíwájú lewá ninú irú igbéyáwò náà. Bẹ́ẹ̀ ki awọn mejéèji ti wọn balé fì sùúrù ṣe kí oriré inú Irawọ wọn lé tètè wolé kiákiá fún wọn.
-Iwọ́ tò bán retí nkan pàtàkí nínú ayé rẹ, Adúrà nìkan ko kún tó, fí ọpọlọpọ sáàrá ṣíṣe tẹ́lẹ rẹ, kí ó lè tètè rí esí adúrà atí igbinyanjú rẹ ní gbigbá lásìkò toyẹ ni kiákiá. Aṣírí tí pupọ ninu ẹ̀dá ènìyàn kómọ̀ ṣé rè. Gbògbo Irawọ loni sáàrá tí Ọlọ́run Ọba tí pèsè sílẹ̀ fún wọn láti maṣé. Ìwọ náà tẹpa mọ Àánú atí Sáàrá rẹ ní ṣíṣe kí iyatọ lé tètè dé sinú ayé rẹ bẹ sini kí Ọlọ́run lé tọ yín sọ́nà bẹ́ẹ̀ dárí rẹ síbi óòre ayé rẹ Lásìkò.