14/01/2024
ONIWASU:- BRO STEPHEN
AKORI:- PADA SI ỌDỌ OLORUN ẸLẸDA RẸ.
LESSON:- LUKE 15:18-19.
Igbe-aiye laini Jesu gẹgẹ bí Oluwa ati Olugbala jẹ ririn ninu ewu.
Ìpinnu tí o dara ju fún eniyan l'aiye nipé, ki eniyan pinnu lati pada sí ọdọ Olorun ẹlẹdàla rẹ.
Ọjà aiye ko ni pẹ tu mọ, pinnu lati fi ara rẹ ṣe gẹgẹ bí ọmọ oninakuna.
Luku 15:18-19 "Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ;
[19]Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ"
Ojojumọ ni Jesu nṣọ̀fọ lori awa ẹlẹsẹ, ko ba ti dára tó, ti orun ba le yọ ayọ lórí ìpinnu rẹ loni wipe, o di ọmọ Olorun.
Luku 15:7 "Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.."
Jesu Olugbala npe ọ nitori ko fẹ ki o segbe.
Eleyi mu mi rántí itan baba àgbẹ (farmer) kan, ti o ri ẹyin asa (eagle egg) kan ni oko rẹ, o mu ẹyin yi wa sile bẹni o da ẹyin na papọ mọ ẹyin adirẹ rẹ tó nṣe aba lọwọ.
Nigbati akoko to fún adirẹ na lati pa ọmọ, gbogbo ẹyin to wa labẹ rẹ ni o pa ati ẹyin asa na. Lati kekere ni awọn ọmọ adirẹ yi ti mọ wipe ọmọ asa yi yatọ larin awon.
Ni ọjọ kan, nibi ti àṣà nla kan ti nwa òròmọdìẹ tí yíò fi se ounjẹ ojọọ rẹ, nigbati o boju wo ilẹ láti oke, o ri ọmọ asa kan larin awon òròmọdìẹ tí wọn njọjọ njẹun kiri.
Iya asa yi, wa bẹrẹ sí npé ọmọ asa to wà larin awọn òròmọdìẹ yi wipe, kinni o nse larin awon òròmọdìẹ nisalẹ, ibugbe rẹ kosi nisalẹ, oke ni ibugbe rẹ wá. Ọmọ asa yi gbe oju rẹ soke fún ìgbà àkọkọ bẹni o ri ẹda bi tirẹ loke.
Ọmọ asa yi wa gbiyanju lati fo soke fún ìgbà àkọkọ bẹni awọn òròmọdìẹ to wa nilẹ npe wipe, nibo ni ọ nlọ, o wa bẹrẹ sí nida wọn lohun wipe ibugbe mi kosi nisalẹ, oke lohun ni ibugbe mi wa.
Arakunrin ati arabinrin, Jesu Olugbala ni mo fi iya asa yi wẹ, o npe wa loni wipe ibugbe wa kosi nisalẹ nitori isalẹ jẹ arin awọn ẹlẹsẹ, wipe oke ní ibugbe wa wa.
IBEERE MI NIYI:
1. Njẹ o ṣetan lati jẹ ipe Jesu Olugbala loni?
2. Njẹ o ṣetan lati pada sí ọdọ Olorun rẹ loni bi?
GBA ADURA YI TẸLE MI:
Jesu Oluwa, ran mi lọwọ láti le pada sọdọ rẹ patapata.