05/09/2025
IFA EBE EYONU ASINA AWON AGBALAGBA
ewe ominsinmisin oniitakun,
ao lopo pelu iyere,
ao ge eyele eyikeyi kan si kekeke,
ao fi iyo ati epo se lobe, ti oba ti jin na tan ao ta oyin die si,
ao fi iyere osun te ifa Ogbe-yonu,
ao pe ofore si ao da sinu aseje yen ao koje
OFORE
oyiboyi lawo aye 3x,
ata bagbe lawo ode orun 3x,
adifa fun Orunmila
ni ijo ti n tiko le orun bo wa ile aiye,
ode ile aiye, oba Oṣo, ode ile Aiye Oba Aje,
ode ile aiye oba Esu odara, Oṣo ni nje Orunmila mo oun ni Oṣo?
Ajẹ́ ni se orunmila mo oun ni Ajẹ́,
Eṣu odara ni se Orunmila mo oun ni Eṣu odara,
Oṣo ni oun ni kin nje kẹni ose owo( business) kẹ́ni jere,
Ajẹ́ ni oun ni kii je ki eni o lowo lowo, ki eni ori aiye se,
Eṣu odara ni oun ni oun ma nfi aburu ṣe eniyan ni ode aiye,
Orunmila ni oun fi Ogbe yonu be yin lode aiye,
eje kin nkan mi o ma dayo,
ki ema le ba nkan mi je mo
nitori a kiifi eyele ṣe irana oku,
ki emale fi nkan semi laburu,
ti a ba fi oyin se obe didun lon dun,
ki oro emi Lomo L oma dun mo yin ninu,
ki won ma gbe owo nla nla ọwọ won fun mi, omode kiifi oyin senu kosin tọ́,
agbalagba oni fi iyo senu ko poṣe,
ati igi ati opẹ̀ lon sanu iyere
ki eyin omo araye ma se anu emi Lomo L lati Oni yi lo, tapatun tapasi ni eyele fi nko ire wole, ogbo eyele kan kin ni eran osi lara, ifa ma je kin mo osi
ogbe yonu loni ki gbogbo omo araye oma yonu si mi lati oni lo... ase ase ase.
Fi adura rẹ ranṣẹ