18/08/2025
ADO META LADO IYA AGBA
Eku eda meta
Odidi atare meta
Eye ega meta
Eye kowe meta
Eye adan meta
Opolopo ila jije
Oga ibile meta
Ikoode meta
Ado meta
A o fi nka tinrin lu ado kan legbe , a o ki ikoode kan bo ti ko ni wole tan , a o fi obe ti o mu la ado keji si meji , a o fi ikoode kan bo laarin , a o lu ado keta fo , a o ko nile , a o fi ikoode kan to ku si , a o ko awon ado meteeta tele ape , a o ko gbogbo nkan ti o ku le lori , a o ko opolopo ewe alupaida bo lori ti ko ni han , a o fi epo pupa yi aaro ti a o fi jo ka , a o jo , a o lo , avo te ni ifa osa meji laarin , irete olota legbe otun , otura meji legbe osi , a o wa pe gbolohun re si , a o ro sinu sere , a o pa abo adie dudu ati eyele to ni irun lese si ara ado na , a o le iye adie ati eyele yen mo ara ado na
Ofo re .......
Irinfin lawo inanaran , alawo ko se , Olorun ba mi leru , awo won ni jeje , eni ni Olorun o ja , babalawo ila , eyin iya mi osoronga mo pe yin ooo , ki e da mi lohun loni , eyin iya mi osoronga , e da mi lohun , ki e da temi si rere laye , apada loni ki e pa rere temi ....omo ... da si odo mi , eyin iya mi osoronga , ado meta ni ado yin , okan bale , o fo , okan bale , o la , okan to ku ni e fi ntanna oju yinrin - yinrin , won ni asure fi ara re yi epo ni oruko ni oruko ti a npe eyin iya mi , eye a bi iye he - he - he ni a npe eyin iya mi , ogbingbin lohun hun - hun - hun la npe eyin iya mi , ogboya lohun a ta soso jako la npe eyin iya mi , emi omo lufe ni mo wole de , eran gbigbe ni mi , eran tutu beje - beje ni ki e wa lo , awa yin ni a jo pe , awa yin ni ajo je , awa yin ni ajo mule ni ojohun ana , eewo orisa , a ki ba ni mule , ki a da ni , awa yin la jo dogbo , ogbon wa wonu ogbon , eye wa wonu eye , kowe eee , 3 x , kowe eee , eyin ogbingbin nife , kowe nke , eye aje ko ha , ogbingbin - hin - hin nife , kowe nke , adan de , alaroye eye , igbe iku ko kan mi ni eye adan nke , oosa meji eleye , irete olota eleye , otua meji eleye , eleye ma binu , eleye ma ma se ja , emi yin ni a jo pe loni , emi na di eleye loni , aje rere ni ki nma ri , aje rere ni ki o ma ri mi , ati adura bi a ba se fe
A o po die mo ose ti yio to wa we fun ojo meje , a o ma fi eyiti o ba ku go eko tutu mu ti a ba ti nwe tan
A ko gbodo sun mo obinrin fun ojo mejeeje , leyin na , a ko gbodo sun mo obinrin lojo ti a ba fi fo eko tutu mu o
Obinrin kii lo ise yi o
odu ifa re...
Irete olota ni owo otun
Otura meji lowo osi
Osa meji laarin