
27/04/2023
AGBO ATI SAARA YIYO KURO NINU ISORO ATI IDIWO TODAJU
Iyo didi meje (ti won ndi ta ni oja)
#100 meje,
Epo-pupa die,
Ewe iyalode funfun tutu oojo ti o pupo,
Eyin adie ibile kan,
Kainkan ibile kan,
Ewe orijin tutu oojo ti o po pupo,
Ose dudu iwe eekan,
Ori olongbo kan,
Ikoko agbo tuntun nla kan.
SISE RE:-a o fi eyin adie ati ori olongbo na tele inu ikoko agbo na, a o wa ko ewe iyalode funfun ati ewe orijin na le lori, a o wa bu omi ti yoo to wa we sinu re, a o wa fi epo pupa yika aaro, a o wa gbe ikoko na le aaro na, a o wa se ti yoo jinna dada, ti o ba jinna tan, a o so sori ada(cutlass) ninu ibaluwe, a o wa yan. Leyin eyi a o wa gun ewe orijin na mo ose dudu iwe eekan, ti a o wa fi ose ti a gun na sori kainkan ibile na.
Lati owo The Spiritual Herbal Power To Do Success.
AKIYESI PATAKI:-ale ni won nwe agbo yi.
WIWE RE:-a o koko fi epo pupa pa gbogbo ara wa lati ori de isale, a o wa we agbo na pelu ose ti a gun na pelu adura itusile.
Bi a ba ti we agbo na tan, a o bo epo eyin ti o wa ninu agbo na, a o wa bu eyin na si meji, a o wa bu die ninu pupa inu eyin na fi sa aarin meji ori wa lemeta lati iwaju lo si eyin, a o wa je eyin toku. Leyin eyi a o wa lo sun lai jade sita mo rara, ti o ba wa di owuro ojo keji laisoro si enikeni, a o wa fi iyo mejeeje ati #100 meje na ma nu ara wa nikookan, ti a o si ma so pe Ti enikan badi iyo loja, enikan ni tu nile, aditu ni a ndi iyo, gbogbo isoro ati idena aye emi lagbaja omo lagbaja ki o ma tu, nitori enikan ki i ba aje binu, a o wa se adura itusile lopolopo, leyin eyi a o wa lo fun awon onibara meje ni awon nkan yi, onibara kan iyo kan, #100 kan.
Iwo ti o bafe ki o je fun o, ma so pe "Agbara aye kookan koni ka Babalawo Awoshola Apena.