08/07/2025
Obara Ofun
☸️☸️☸️☸️☸️☸️
Òpápárá lawo òpápárá
Àwòrò kéreré kòdosù
A difa fun olójúkòtì a bu fun alápákòmú lojo ti won nfojojumo nje èbe (iyan) nile olofin.
Olofin ni abiku nda laamu to wa ranse si àwon babaláwo wípé ki won wa difa fun oun latari ki o baa le ri isegun lori "abiku" to nda laamu, nigbati àwon babaláwo olójúkòtì ati alápákòmú dele olofin "won gbodo wale agbede orun ro" a ko rifa meji, Obara Ofun ni won ri, won wa sofun olofin wípé kofi okan bale ki o masi beru mo won ni omo olofin koni ku mo, won ni ki olofin gbe iyan wa ki won fi rubo, olofin gbe iyan jade àwon babaláwo joko ti iyan won je iyan laifi rubo ti won sofun olofin wípé won fe ru, ko ju bi osupa kan si, omo olofin miran tun fo sanle o tun ku, olofin tun ni ki won pe àwon babaláwo náà fun oun ki won tun wa ba oun difa nitoripe omo oun si nku o, igbati àwon babaláwo tun de won tun difa won tun fi olofin lokan bale won tun ni iyan ni oun ebo, olofin tun gbe iyan kale sugbon seni àwon babaláwo tun je iyan lalaifi rubo kankan, ko tun pe osupa meji ikan ninu àwon omo olofin tun ta "teru nipa", olofin ni ah! Afigba ti omo oun tun ku, O wa fi ibanuje ranse si Òrúnmìlà wípé ki o wa difa fun oun, bee ni olofin ti pinnu ninu okan re wípé eleketa yi ni oun yio fi imun babaláwo eyikeyi to ba kuna danrin, olofin ti mu iyan o ti fi bo gbogbo ara oku omo re o gbe sinu igba, Òrúnmìlà ree ko to lo sile olofin o ti difa, oke iponri si ti kilo fun wipe ki o mase je èbe (iyan), nigbati Òrúnmìlà maa dele olofin baba gbefa kale ee gba! A ko ri ifá meji Obara Ofun lo jade sita, Òrúnmìlà ni ah! Oni òpápárá lawo òpápárá àwòrò kéreré kòdosù a difa fun olójúkòtì a bu fun alápákòmú lojo ti won nfojojumo nje èbe nile olofin, Òrúnmìlà ni oke iponri oun ti ni ki oun ma je èbe, Òrúnmìlà so nkan ebo miran ti o maa ru fun olofin baba si dide o lo, olofin ni ah! Olotito ni baba yi, o wa tun ranse si àwon babaláwo ti tele yen wipe ki won wa difa fun oun o, nigbati ti won tun dele olofin, àwon náà tun difa won tun ni ki olofin saa fi okan bale won ni omo re koni ku mo won ni iyan ni ki o tun ru lebo, olofin ba wole o gbe iyan ti oku omo wa ninu re yen sita funwon, àwon babaláwo tun joko ti won tun bere si iyan jije, seni won je iyan tititi ti won je de ibiti oku omo wa, eru bawon won fo dide won fe salo sugbon olofin di won mu, olofin ni afi dandan ti won baje oku omo oun loun a to fi won sile, olofin ni àwon lo npa omo oun nitori ki won baa le maa ri iyan je, bi olofin seni ki won lo ree tiwon monu tubu niyen, won ni ki won jeki won maa tufa da sugbon olofin ni won ki ntufa da mo, nje alawo ni yio maa yin ifá, ifá ni yio maa yin Eledumare Oba, ifá ma de aláse
Ebora abìse
Òpè abìse wàràwàrà.
Lati igba náà ni omo olofin koti ku mo o.
Idi niyi ti eniti odu Obara Ofun ba bi nigbodu ko se gbudo maa je iyán.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe gbogbo abiyamo koni mo saare omo re, ako ni foju sunkun àwon omo wa, àwon àlùbà buburu ti npa omo eni je koni mona ile wa o, gegebi oni se je ojó aiku ako ni ri ogun iku ojiji lori wa, omo wa ati àwon ololufe wa patapata, ao dagba ao dogbo laye ninu ola ati idera lase Eledumare