
02/07/2025
Good morning my people, how was your night? Hope it was great, may we be blessed and favoured today, whatever will lay our hands on today shall be fruitful.
Let us use this holy corpus of Ọwọnrinṣogbe for today's prayer.
Hear what the corpus said:
Biijobiijo bi ayọ bi ayọ a message for maize when maize was going to annual farm, maize was advised to offer sacrifice so that maize could produce good and plenty seeds, two kola nuts,...... cake beans, he-goat, fly whisky and ifa leaves and she complied, when maize reached the annual farm, they planted it, maize started germinating within five days and esu odara started wetting her bottom with the fluid of the snail that maize offered as a sacrifice, maize started germinating very fast and later produced seeds and esu ọdara also put the fly whisky that maize offered as a sacrifice too on the hands of maize's seeds, maize produced good seeds and plenty clothes, maize started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising Eledumare.
My people, I pray this morning that this new day will bring us everlasting joy, may we never experience any sorrow in our lives, all our seeds will come out in flying colours also our works/businesses will fetch us a suitable income and we shall end up this month with great achievements Àṣẹ.
YORUBA VERSION:
Ẹkaarọ eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, oni yio sanwa sowo, sọmọ, sile kikọ, mọto rira, ire ọkọ/aya ati aiku baalẹ ọrọ̀ Àṣẹ.
Ẹ jẹki a fi odú ifá mimọ Ọwọnrinṣogbe yí ṣe iwúre ti aarọ yi.
Ifa naa ki bayi wipe:
Biijobiijo bi ayọ bi ayọ a difa fun agbado lọjọ ti nroko alere ọdún, wọn ni ko káraálẹ̀ ẹbọ ni ki o wa ṣe nitori ki o baa le ko ire bọ wa sile, obi meji, eru eko,.......... irukere, obuko ati igba ewe ayajo ifa, agbado kabomora o rubo won si se sise ifa fun nigbati agbado doko aloro odun won fi fole nigbati o maa di ojo karun agbado bere sini nwu Omi igbin to fi rubo lojo kini ana esu odara nto Omi naa sidi agbado, agbado wa dagba o yọmọ, irukere to tun fi rúbọ lọjọ kini ana èṣù ọdara fi le Ọmọ agbado lọwọ, awọn Ọmọ agbado dagba wọn dògbó wọn si tobi daradara inu agbado dun o wa njo o nyọ o nyin babaláwo àwọn babaláwo nyin ifa, ifa nyin Eledumare oni riru ẹbọ a maa gbeni èrù àtùkèṣù a maa da ladaju njẹ ko pẹ ko jìnà Ifá wa bami ni jẹ̀bútù ire njẹ jẹ̀bútù ire ni a nba awo lẹsẹ ọbariṣa, wọn wa fìyẹ̀rẹ̀ ohùn bọnu wípé; njẹ kini agbado mu toko bọ?
Igba Ọmọ lagbado mu toko bo igba ọmọ,
kini agbado tun mu toko bọ?
Igba aṣọ lagbado mu toko bọ igba aṣọ.
Ẹyin eniyan mi, moṣe ni iwúre laarọ yi wípé ọrọ ayọ ati idunnu ni yio jẹ tiwa, ako ni ri ọrọ ibanuje igbesi aye wa yio so eso rere, gbogbo adawọle wa yio yọrí si rere ninu loni, ao ni ayọ ayeraye aaaseee.
ÀBỌRÚ ÀBỌYÈ OOO.