BaBa ASEYORi

BaBa ASEYORi Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from BaBa ASEYORi, Health & Wellness Website, Lagos.

BABA ASEYORI TRADOMEDICAL HERITAGE
You can contact us for any of your health & spiritual problem such as: MENTAL DISSORDER,EPPYLEPSY,FIBROID,STROKE,PROGRESS IN BUSSINESS,LOVE SOAP,ETC....08038692880/08050673323

OSE KOKORO ARA(SKIN RASHES SOAP)================●Tanmona●Kuruna●Ifo/Eela●Komo buss stop●Pimples●Ete●Lapalapa ●EtcKokoro ...
24/08/2025

OSE KOKORO ARA
(SKIN RASHES SOAP)
================
●Tanmona
●Kuruna
●Ifo/Eela
●Komo buss stop
●Pimples
●Ete
●Lapalapa
●Etc

Kokoro ara je ohun ti o ma nmuni ho ara ti yi o si ma dun mon ni ni akoko na, eyi a sima mu idojuti bani ni Igbamiran nitoripe osese ki a ti gbagbe pe ita tabi Awujo kan ni a wa.

Nigbamiran, Eniyan le ho ara t**i ti Gbogbo Ara yi o si bere sini bo tabi ki o ma seje, Bi a ba si se nho ara yi si ti o ndun moni, bee nani kokoro na yi o ma po si.
Bakana, iwo ti o ni Ifo tabi Eela (Eczema) ni ara, ti o ti wa lo oniruru Ogun tabi Ose ti ko lo, mo ki e ku orire pe o se Alabapade ohun ti mofe ko e loni.

Ose yi dara fun omode ati agba, ti o ba bere sini lo Ose kokoro yi, o damiloju pe waama fi ope fun Eledumare laarin ojo meji si meta ni.

AWON OHUN TI AO WA
●Ewe Laa Pupa ( Ricinus communis)
●Ewe Botuje (Red Jatropha leaves)
●Aidan (Prekese)
●Imi ojo (Sulphur Rock)
●Ose Dudu (Black soap)

BI AOSESE
Ao gun Gbogbo Eronja yi papo dada ti o kuna, ao fi ose dudu ko,ao wa gun papo dada ti yio kuna.

Ao mafi ose na we ni Owuro ati Ale.
Iwo ba bawa share re fun Anfani Awon Elomiran

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

AGBO FUN GBOGBONISE ==================●Egbo Awogbarum●Egbo Paran●Epo Aganho●Epo Agbon●Karandafi●Egbo Akogun●Egbo Opon●Ep...
22/08/2025

AGBO FUN GBOGBONISE
==================
●Egbo Awogbarum
●Egbo Paran
●Epo Aganho
●Epo Agbon
●Karandafi
●Egbo Akogun
●Egbo Opon
●Epo Ahun
●Epo Mangoro
●Mentol

Agbo yi dara lopolopo fun oniruru Aisan ti o banseni, paapa julo Awa ti Aisan kan tabi meji ti nba finra lojo ti o ti pe, ti ati wa lo oniruru Ogun ti o ko, ti kolo, Ti o ba gbiyanju Agbo yi, o dami loju pe wa ma gbe Titobi fun Oba ti o seda Ewe Ati Egbo ni,Toripe Agbo ti awon Babanla wa manse lati fi toju Oniruru Aisan ni Laiye Atijo.

AGBO YI NSISE FUN AWON AISAN BI:
●Aito Eje
●Paja-Paja Owo/Ese (paresthesia)
●Aikori Orun sun (Insomnia)
●Ori Fifo Gbogbo Igba (Constant Headache)
●Ara Riro (Body Pains)
●Aisan Iba (Malaria Fever)
●Aya Jija (Palpitations)
●Ki Eniyan o maru/magbe (Weight loss)
●Isan Fifaniso (Muscle pain)
●Ki Eniyan o male Jeun (Inability to Eat)
●Etc (Ati Bebelo)

BI AOSESE
========
Ejeki a fo gbogbo awon Egbogi yi nu ki o mo dada,ki a wa se ki o jina dada fun bi Ogbon Iseju, leyin ogbon iseju ejeki a so kale ki a wa se ( Filter) pelu Ase, ki a ro sinu ike ti o bamo dada.

LILO RE
======
Gass cup kan ni Owuro ati Ale leyin ti a bati jehun tan.
Mobe Eledumare ki o ma sanmi ni dede Esan ti bato simi🙏

Gbogbo wa o nifi Aisan Logba oo 🙏
Iwo na bawa share re fun Anfani Awon Elomiran.

Fun Ibere Tabi Ohunkohun.
08038692880

SARA ISEGUN OTA TODAJU====================●Obi (Cola Nut) 9m 7fm●Orogbo (Bitter Cola) 9m 7fm●Iyo Didi (Tied one not Satc...
20/08/2025

SARA ISEGUN OTA TODAJU
====================
●Obi (Cola Nut) 9m 7fm
●Orogbo (Bitter Cola) 9m 7fm
●Iyo Didi (Tied one not Satchet) 1

Iwo ti Ona di fun, tabi iwo ti o wa lori idubule Aisan, tabi iwo tonwa omo, tabi Promise and Fail ni ti e, iwo gbiyanju ki o se Sara yi ki o wa wo bi Olohun Eledumare o se Gbe o leke awon Ota.

Tani Ota gan?
Ota ni Eni ti kofe ki Eniyan o se ohun rere ninu Aye yi, tabi Eni ti o nwa iku tabi Ifaseyin re, Sugbon mofe ki a mope ti ao bati ja Ajabo lowo Ota ao le ribi lo ninu Aye yi, Owe awon agba sope, Eyinkunle l'ota wa,Inu ile ni Aseni ngbe, Eyi tumosi pe, Awa arawa ni Ota Ara wa, eni ti korini ri tabi ti komo eye ti o suni, kole layelaye je ota Eni, Ota nbe ninu Ile, Ninu Ebi, Ninu Ore, ati lawujo

Eledumare Oba ti o da aye gan je ki o yewa pe ki a Sora fun ota, nitoripe, Agbara ota lefa ifaseyin fun kadara eni, bakana, Ti o ba lo joko Tentele ninu aye, ti o ba jeki Ota o ni ikapa lori re ti o fiku (Die), o sese fun Ota na ki o pada ronu piwada ki Eledumare o si forijin (Forgive) Ota na, Sugbon iwo si tidi Eni Ile (Die)
Fun Idi eyi, Akiiduro ninu Aye yi o.

Aikomo iye ohun ti Eledumare lese sugbon ti koni se, O kapa lati majeki ipa ota o kawa sugbon koni se ni, Bee osi kapa lati so Gbogbo wa di olowo sugbon koni se ni, Iwo loku si lowo lati kepe Eledumare na, ati lati ja ajabo lowo ota re o.

Kiise Gbogbo ota lonse Ogun Tabi gbe Ebo lori isubu eni o, sugbon Olohun Eledumare fun Elomiran ni Agbara oju (Sight Power), Elomiran Agbara Ahon (Tongue Power), Elomiran wa ti o jepe Oju buruku (Sight Power) lasan ni ota finwo iru eni na, ti nkan o sima buru fun enina latara oju buruku ti ota fi nwo.Bakana, Inu bibi
(Agressive power) lasan ti Ota nbi si Elomiran lonfa Ifaseyin sinu Aye Elomiran t**i di oni ti oro ayebre o sini ojutu.

Opo ti se bee, ti won ti koja lo si orun osan gangan latara Ikolu Ota, sugbon awa ti a wa laye si tun ni Ore ofe lati ja ajabo ki Ipa ota o mase Kawa o!

Mogba ladura, Ipa ota, Ati Imoran won o nise lori Aye Gbogbo wa o🙏

BI AO SESE
Ao wa Obi Eyikeyi mesan fun Okunrin 9, meje fun Obinrin,Orogbo na 9 fun Okunrin meje fun Obinrin, Bakana Iyo didi Eyokan pere.
Ao to obi na ati orogbo yen tele arawon ao wa fi iyo si arin re, ao wa Sure (Pray) si, ao Toro pe "OBI NI BI IKU, OBI NI BI AARUN, ki Obi o Biku fun mi, Bi Arun, Airije,Airimu, Etc.

Bakana ao tun sobayi pe:
ADITU LAADIYO, BI OMO ARAYE BARA IYO LOJA,OMO ARAYE A SI TU TI WONBADELE,ki ishoro Aye mi o Bere situ,airije,airimu, aibegbe pe,etc.

OROGBO NI ELEBE SANGO, BI SANGO BA PANI APAGBE NI, Gbogbo ota ti o nroku romi, ki won o ma nisho lorun demi ni, etc.

Okunrin ojo mesan, Obinrin ojo meje nibao fi se ise yi o.

Ao mafi Obi Eyokan pelu Orogbo kan se Sara ni Owuro kutukutu ki orun o to Jade, be ni aosese fun ojo meje/mesan, ojo ti o bape ao wa se sara na pelu iyo eyokan ti o ku.
Pelu Agbara Olohun Oba, Ipa ota o ni kawa, Ona o si, Bee Ona o la fun wa oo.

Iwo na bami share re fun Anfani Awon Elomiran
Imoran ota koni se lori awa ati Ebi wa o🙏

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

IWULO EGBO AKOGUN=================●Arun Ibalopo (Std Infection)●Ogbe Inu (Ulcer)●Aran Eyikeyi (Worm)●JediJedi (Pile)●Ito...
17/08/2025

IWULO EGBO AKOGUN
=================
●Arun Ibalopo (Std Infection)
●Ogbe Inu (Ulcer)
●Aran Eyikeyi (Worm)
●JediJedi (Pile)
●Ito Suga/Atogbe (Diabetes)
●Ale (Man Power)
●Onaofun Didun (Throat Infection)
●Narun (Hives)
●Ori Fifo Tulu (Constabt Headache)

Awon Baba wa se Akitiyan ati Igbiyanju pupo lori Wiwa Imo (Research)lori lilo Ewe ati Egbo Bakana lori fifi idi awon ona ti a le gba lo won fun Itoju Oniruru Iwosan mule fun Anfani wa.

Olohun Oba ti o seda Ewe ati Egbo sedare fun iwulo Iwosan fun awa Eda ni.

Mofe ki a mo Amodaju pe, Kosi Aisan/Arun kan ti Onbe ninu Aye yi ti kosi Iwosan re Ayafi Eleyi ti Ao bati se Awari Iwosan re loku.
Bakana, gbogbo awon Ogun oyinbo ti a nlo, latara Ewe Ati Agbo ni, awon ona ti wongba se awon Ogun yi ni o yato.

●ARUN IBALOPO: Arun Ibalope je Arun ti o wopo lawujo wa, bakana Arun yi pinsi Awon ona ti o po, kiise Latara ibalopo nikan ni atile ko Arun yi o awon ona ti a ti le ko po gan, koda, kiise Gbogbo arun yi ni roba idabobo (Condom) le kapa re ki a ma bako sugbon eyi kiise Alaye ti a le maso loni,ao ma se Alaye re nigbamiran.

Ki Eni na wa Egbo Akogun (Carpolobia lutea) ki o po,bakana Egbo Atori,Ki a gun ki o kuna dada, ki a wa ha Fofo olokun 3 si,ki a sa (Dry) ti o ba gbe tan ki a tun gun dada, ki a malo ni sibi imuko 1 Owuro ati Ale leyin onje.
Gbogbo ohun ti o banje Arun Ibalopo ni Egbogi yi o Fo (Wash) danu patapata.

●JEDIJEDI: Ati omode ati agba ni ko bo lowo JediJedi latara awon apoju ohun aladun ni jije, Aisan jedi ti so opo Okunrin di Eniti kolese dada to mo lodo aya re. Elomiran Isoro Eyin didun ni.
Ti Jedi pa po ni ara,o le fa awon apere wonyi:
●Eyin Didun (Back pain)
●Ara Riro (Body Pain)
●Aikori Orun sun to dada (Insomnia)
●Inu kikun (Noisy stomach)
●Idakole (Erectile Disfunction)

Ki Eniti Jedi ba ndalamu o wa Egbo Igi yi,Pelu Egbo Jedi Ege, Baaka, Egbo Gboingboin ati Eso Abere niwonba, ki o kii lagbo.mimu ni idaji glass cup ekan lojumo.

●ALE (MAN POWER):
Okunrin ti o base Agbo yi Iyawo re o makan Saara (Praise) si ni Nitoripe Osise gidi ni
Ki eni na o wa Egbo yi Egbo Akogun, tutu,
(Carpolobia lutea) Egbo Atori Tutu, Ogede Agbagba dudu, Ataale (Ginger) Ki a wa gun Gbogbo re Papo, ki a mafi je Ogede nigba ti o ba wuwa.

●ARAN EYIKEYI (WARM): Aisan Aran je aisan ti o ma nyo omode ati agba lenu, tikiije ki Eniyan o gberu, Orisirisi Aran lowa,
●Aran Otili (Pinworms),Eleyi losaba mandamu awon Omo kekeke ti o sima nfa Arun (Infection) fun omode
●Aran Mujemuje (Hookworm),Arab yi buru gan tori ohun manni ori somusomu ,Bakana enu re gun ti o si mu bi abe, Awon Aran yi lomanse ijanba fun awon ifun latara kikolu won ti won o sima je won.
Aran Oginsa,Eyi ni Awon ti kiijeki Oyun o duro lara Obinrin, Aran yi ma nba oyun jeni, Gbogbo igbiyanju ti Eniti o nwa oyun banse,Aran yi kiijeki Oyoun o duro rara.

ki a ge Egbo Igi yi kekeke sinu ike ti o bamo leyin ti a ti fo pelu omi, Ki a wa kii (Soak) pelu omi osan wewe (Lime water) ti a fun funrawa lasan, Ki Eni ti o bani Eyikeyi Aran (Warm) o maamu Sibi imuko kan ni Emerin (4 times Daily) Lojumo.

●ITO SUGA (DIABETES): Aisan ITO SUGA je Aisan ti o buru gaan ti o si ma nyara soni di idakuda tikobari Itoju ti o peye fun,Aisan yi pinsi Ipele meta (Type 1,2 and 3) ti awon Ipele yi si niunse pelu Apoju ati Aitkoto Suga inu Eje wa
(High Blood Glucose) Tabi ti koba pese Asolin rara (Insulin), Eyi lefa ki Eniyan o maru ki o magbe.

Ki Enina o wa Egbogi yi, pelu Eso Abere, ki a gun won papo ki o kuna dada,ki a sa (Dry) ki o gbe, ki a tunlo dada kio kuna. Ki Eni na o malo pelu Lipton TEA laro ati lale. Pelu ogo olohun oba Iyipadada de ba Enina.

Kiise Gbogbo awon Iwulo Egbo Igi yi ni a le se Alaye re tan sugbon ao tun ma Tesiwaju nigbamiran.

Iwo na bawa Share re ki o le se Anfani Fun Elomiran!

Gbogbo wa o nifi Aisan Logba oo 🙏

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

IWULO LILO OMI AGBON FUN IWOSAN ===========================●Ito Sugar (Diabetes)●Ifunpa Giga (Hypertension)●Oyi Oju (Diz...
11/08/2025

IWULO LILO OMI AGBON FUN IWOSAN
===========================
●Ito Sugar (Diabetes)
●Ifunpa Giga (Hypertension)
●Oyi Oju (Dizziness)
●Kindinrin (Kidney Stone)
●Ti Omi ara bag be (Hydration)
●Isoye (Brain Booster)
●KOKORO ARA (SKIN RASHES)
●Aisan Okan (Heart Issue)
●Etc

Gbogbo Igi ti Eledumare da si ori ile pata ni won ni Iwulo, Sugbon iwulo ti o wa ninu omi Agbon tun jeki a ma gbe Osuba fun Eledumare!

Ninu Iwadi Imo Ijinle, Aridaju pe Omi agbon ni awon Eronja Afaralokun Vitamins, minerals, zinc, Pottasium,B6, Magnesium ati bebelo, Sugbon Opolopo wa ni ao ma ona ti a le gba lo fun iwosan.

Ni Ijohun ana,awon tiwon bi wa mansope kodara fun omode lati mamu omi agbon pe kiijeki omode o ni Iye ninu 😀 Eyi koribe rara o, Omi agbon dara lopolopo lara omode, o si tun ma nfun omode ni okun ati agbara gidigidi.

●ITO SUGA (DIABETES)
Ejeki a wa omi agbon ti o po dada, kia ja Ewe Ewuro ti o po dada, ki a wa fi omi Agbon yi gbo dada,ki a se (Filter) ki a mamu ni Gass cup kan lowuro ati Ale leyin Ounje.

●IFUNPA GIGA (HYPERTENSION)
Ki eni ti o bani Ifunpa Giga o ma je awe Alubosa Ayu (Garlic) kan ni Owuro kutukutu, ki o wa mu Omi agbon le lori, bakana ki o se e be ni ale ki o to sun, eleyi a ma se iranlowo pupo fun eni ti o bani Ifunpa Giga.

●KINDINRIN (KIDNEY STONES)
Ki e ti o bani Isoro pelu Kindinrin o ma mumu Omi agbon dada, omi agbon a ma fo gbogbo idoti ti o bawa ninu Eje,Bakana a ma fo Gbogbo idoti ri o va wa ninu Kindinrin pata.

●ISOYE (BRAIN BOOSTER)
E jeki a wa omi agbon ati oyin gidi ki won o je dede Odiwon kan na, ki a wa mix mejeji papo, ki a ma mu ni sibi kan lowuro kutukutu ki a to jehun.

KOKORO ARA (SKIN RASHES)
ki eni ti o bani Kokoro Ara o mafi omi agbon pa gbogbo ara re ki o to sun lale,ki o si tun ma mu omi re bakana,ti o ba we ta laro,ki o tun fi para, mi o fe mo bi kokoro na se fe ri, yi o lo patapata.

Omi Agbon ni Iwulo ti ao le ka tan
Iwo na bawa share re fun Anfani Awon Elomiran.

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

ISE ITAJA TI A FINLE OKUTA JINA========================●Bara Kekere 1●Iyo Isebe Didi●Owu dudu ●Owu Funfun ●Owu PupaOkuta...
04/08/2025

ISE ITAJA TI A FINLE OKUTA JINA
========================
●Bara Kekere 1
●Iyo Isebe Didi
●Owu dudu
●Owu Funfun
●Owu Pupa

Okuta je nkan ti o le yara soni di Ero Eyin ti eda o bamura si dada, O le soni di Eniyan yepere lawujo ni kiakia.

OHUN TI ANPE NI OKUTA: Nipe, ki Eniyan o pate Oja sile, ki o wa jepe Esinsin ni nyowo Imi ni oro oja na di, ti kosi ribe Lati Eyin wa, sugbon Lojiji ni nkan yi, ti Oja na si bere sini reyin, ti kowasi Akojo kankan Lori Awon Oja na.

Ona meji ni Okuta ma ngba wole sinu Oko Owo Eda.

(1) ISE AYE: Eyije Ona kan ti Aye a ma gba Muni nidi oko owo eni, Eyi a masele latara Owu Owo Jije, Boya iwo nta dada ju ti awon Arayoku re lo ti eyi sile faa kiwon o maa binu eni, Tabi ki won o da Okuta sinu oko owo eni.
Igbamiran,Iwo lema ri ti Enikeni ro rara,sugbon won kanle sadede maa binu Olohun latara bi olohun oba se nke o.
Fun idi Eyi, Won a ma na owo Okuta fun ni ti o jepe, ti Eniyan bafile da owo na papo mo awon owo ti oku,mofi Oba ti o dami Bura,Okuta ti bere sini wonu oko owo Eni na niyen o.

(2) AFOWOFA: Kiise Gbogbo nkan ni Aye ma nfinse Eniyan nigbamiran oo, Iwo ti o pate oja kale, ti o ni Aajo bi a se nse oyaya mo Awon Onibara eni, ti o jepe Gbogbo igba ni iwo ma nleju kokoko si awon onibara re, maje ki nto o, Eyi le fa Ifaseyin fun Oko owo re dada, O sile faa ki Okuta o wole si o lara oo.

Bakaana, awon Omo ti won nbani sise, A kii gboju mo won rara, Suuru ati Oyaya ni o ye ki afi ma ba Iru won se.
Nigbamiran, Iseda awon omo ti o nbawa sise lema Le awon Onibara wa sun siwaju latara Irufe Awon iwa ti a ba nhu siwon.
Erin Pelu Oyaya ni Ogbon Oko owo ni sise o

BI AO SESE
Ao wa Bara kekere ti koiti gbo rara, ao wa pa ni pansa, ao wo Gbogbo idoti inu re danu, ao fi Owo Aje Eyokan si ninu, ao wa da iyo Isebe si ti yi o kun dada, ao fi omori re da pada,ao wa fi awon owu meteta na we dada ti koni han mo rara.

Ona meji niba le gba se Ise yi.
Ki a lo bo mole ni Iwaju shop wa.
Ki a gbe ise yi sinu Ape ijogun, ao jo, ao lo, ao pomo ose dudu.
Ose yi ni ao fima fo shop wa.

Pelu Agbara Olohun Oba Ti o seda Ewe Ati Egbo,
O obere sini mari Iyato laarin Ojo meta.

Okuta o niwole to Gbogbo wa o 🙏🙏🙏

Iwo na bawa share re fun Anfani Awon Elomiran.

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

IWULO ATI ANFANI EWE IPIN (FICUS EXASPERATA LEAVES)======================Ifunpa Giga ( High Blood pressure)Warapa (Epile...
02/08/2025

IWULO ATI ANFANI EWE IPIN
(FICUS EXASPERATA LEAVES)
======================
Ifunpa Giga ( High Blood pressure)
Warapa (Epilepsy)
Aisan Okan (Heart Diseases)
Aikori Orun sun (Insomnia)
Narun (Hives)
Oju Sisu (Blur vission)
Arun Ibalopo (Std Infection)
Ara sisan Apoju (Obesity)

Igi Ipin (Ficus Exasperata) je okan pataki ninu Gbogbo Igi ti Eledumare da si ori ile Aye ti o ni awon Oniruru Iwulo ati Opolopo Eronja Asara lokun ninu.

Kosi ibi ti igi yi o si ni orile aye, Igi yi wopo nile awa Adolowo ni Orilede wa (Western Nigeria) pupo ju gbogbo ibi kibi lo.

Ninu Iwadi Imo Ijinle, awon Ojogbon Agbaye fi idi re mule pe "IGI IPIN" (Ficus Exasperata) Yi nsise fun oniruru awon Aisan ati Arun, Paapa julo, awon Aisan ti o ba jemo "Eto Eda Onje ara"
(Digestive System), Bakana a ma nu Adinku ba IFUNPA GIGA (Lower Blood Pressure) ati awon Aisan ti o nise pelu "OKAN"
(Cardiovascular disease).

Awon Ohun ti o je Iwulo po Lara Igi "IPIN" Bi
●Epo re (The Barck)
●Ewe re (The Leaves)
●Egbo re (The Roots)
●Eso re (The Fruits)
●Ododo re (The Flower)

Ohun ti o nseni laanu pupo nipe, Opo awon igi ti o je Ojulowo Igi Anfani ni won ti ge tan pata ninu igbo, Bee, o fe ma si Inu Agbo Ile tabi Eyinkunle, Tabi Adugbo ti Igi yi o si ni ojohun ana, sugbon ati nse Afeku won bayi, koda, Opo awon omo isin ni won o da opolopo igi mo laye ode oni nigbati kofesi ni Awujo wa mo.

Ni ojohun ana, Awon Baba wa a mafi Ewe "IPIN" yi fo (Clean) Wahla Ti won fi nkewu, Bakana Awon iya wa a maafi bo (Clean) Eyin Ikoko Isasun Obe won ti yi o si mo Tonitoni😀

EYI NI BI A SE LE FI TOJU AWON ONIRURU AISAN/ARUN

●IFUNPA GIGA (HIGH BLOOD PRESSURE): Ki eni na o wa Ewe ati Epo Igi yi Lasan ki o po dada, ki o se kibo jina pelu Alubosa Ayu (Garlic) Eyo Marun Pere, ati Ata ile (Ginger) fun bi ogbon iseju (30min), ki eni na o mamu ni Odiwon idaji stainless cup kan ni Owuro ati Ale leyin ounje.

●NARUN (HIVES): Ki eni ti o ba ni Arun yi o wa Ewe yi Eyo mewa pere (10 pieces), ki a gun pelu Eru Alamo, ati Iyere (Tumeric), papo mo ose dudu, ki a wa fi oyin po papo.
Bakana, ki a ja ewe yi ki o po,ki a se lasan ki o jina dada pelu Iyere (Tumeric).
Ao mamu Agbo yi ni owuro ati Ale, ao sima fi ose yi para pelu omi ki a to sun lale, ao ma we danu ni owuro.

●AISAN OKAN (CARDIOVASCULAR DISEASE): Ki Eni o wa Egbo,Epo ati Ewe yi niwonba bi o base fee si,pelu Aidan (Prekese) ao fi obe ge awon igun Aidan yi, Ata ile Pupa (Red Ginger), ao fi obe ha gbogbo Epo ara re, Ao gun Gbogbo Eronja yi papo dada ti o kuna, ao sa ki o gbe, ao kuu (Filter) ao ma ree (Soak) Sinu Omi Gbigbona idaji stainless cup kan gegebi TEA fun bi Iseju mewa Tabi ju beelo (10min or more), ao se(Filter), ao fi oyin gidi
(Pure Honey) sibi kan si. Mimu ni Owuro ati Ale leyin onje.

●AIKORI ORUN SUN (INSOMNIA): Ewe yi lasan ni ki eni na o lo wa, ki o wa lasan be, ki o maamu ni idaji stainless cup kan ni Alale ki o to sun.
Ti e ni na o ba Sora, yi o fe le matosile nibiti yo o gbadun Orun na de😀

Kiise Gbogbo Iwulo/Anfani Igi yi ni a le salaye re tan nitori Asiko, sugbon ao tun ma te siwaju nigbamiran ti Eledumare o ba gba Emi wa!

Mofi Oba ti o dami bura..Agbara nbe ninu Ewe Ati Egbo Awon Babanla Wa!

Mowa be Olohun Oba, ati Aisan ti o kere, ati Aisan ti o Tobi, ki o mafi se Enikokan wa ati omo ati Ebi ati Ara wa ooooo🙏

E ba wa share re ki o le se Anfani Fun Elomiran.

Fun Ibere Tabi Ohun miran
08038692880

AGBO TYPHOID (IBA JEFUN-JEDO)=========================●Ewe Ibepe (Carica Papaya Leaf)●Ewe Agunmaniye (Gliricidia sepium)...
29/07/2025

AGBO TYPHOID (IBA JEFUN-JEDO)
=========================
●Ewe Ibepe (Carica Papaya Leaf)
●Ewe Agunmaniye (Gliricidia sepium)
●Ewe ati Epo mango (Mangifera indica)
●Ewe TEA (Lemon Grass)
●Omidun Yangan (White Pap Water)

Aisan "IBA TYPHOID" je Aisan ti o buru gidi, ti o sile se Iku pa Omo Eniyan ti Aisan na ba gberegede ninu ara tan, Sugbon O seni laanu pe Opo wa ni kii saba kobiara si AISAN "IBA JEFUN-JEDO" (TYPHOID FEVER) yi.

AISAN "IBA JEFUN-JEDO"(TYPHOID FEVER) yi je Aisan ti wopo lawujo wa, Papaa julo Awon Agbegbe ti kobati si Imototo ti o peye, Eniyan a ma ko latara Onje Jije Ati Omi Mimu Ti o ti baje Tabi ti kokoro Aifojuri ti a mosi
(bacterium Salmonella Typhi) ti ye sinu Onje tabi omi na, Bakana ti Ti enyan ba se Igbonse ti Eni na ko fo owo (Hands) re mejeji ki o mo dada, ti o ba ti Owo na bo enu tabi Inu Onje Tabi Omi, Oti di dandan ki Eniyan o ni Ikolu Aisan yi.

Eniyan tunle ko Aisan yi latara pe, Ti Eniyan base Igbonse Bakana Ti ko fo awon owo ( Hands) re mejeji ki o mo dada, ti a ba fi owo na gbe Ero Ibanisoro (Mobile phone) wa, Tabi ohun miran, Ti kokoro yi si ti wa nibe, Gbogbo Eni ti o batun fi owo (hand) re na kan Ero ibanisoro
(Mobile phone) yi tabi ohun miran yi laiko fo owo re ki o mo Tonitoni, ti Eni na bati owo na bo inu Nkan jije tabi inu Ohun mimu, oti di dandan ki Irufe awon ti wonba je ninu onje yi tabi mu ninu omi na o ni Ikolu Aisan yi.

Awon kan a ma sope, kokoro Efon (Mosquito) lonfa Aisan yi.

Rara oo, kiise Kokoro Efon. Sugbon kokoro Efon le fa Aisa IBA LASAN (MALARIA)

Ninu Iwadi Imo Ijinle, A ri daju pe ni kete ti Aisan yi ba ti wonu Ago Ara, a ma yara sare losi inu Ifun Tere "Small intestines" (gut), Bakana, Aisan yi le se akoba fun Edo (Liver) wa, ti Eni na o si bere sini mase Aisan.

Opolopo loma nse Afojudi si Aisan yi, Bee, Aikomo Ogunlogo Eda ti Aisan yi ti ran lo si Orun Airemabo Lairo tele. sibe sibe Awa kan o ma wa sope Sebi "AISAN IBA" lasan ni.

Aisan yi kiise ohun ti a le ma bu Enu Ate lu, Tabi ohu ti a le mawo niran rara, tori o yara gba Emi Eda.

AWON APERE AISAN YI (SYMPTOMS)
===========================
●Ara Gbigbona (High Fever)
●Ori Fifo (Headache)
●Igbe Gbuuru (Diarrhea or Constipation)
●Eebi (Nausea or Vomiting)
●Otutu (Chills/Cold)
●Iko (Cough)
●Ki Eniyan o male Jeun (Loss of Appetite)
●Isan ara fifaniso (Muscle Aches)
●Isale inu kikan (Stomach/Abdominal Pain)
●Kokoro Ara (Rashes.usually on chest/Stomach)

BI AOSESE AGBO YI
==============
Ao ja awon Ewe yi, Bakana ao pa Egbo Igi yi, ao fo won nu pelu omi ti o mo dada, Ao ko sinu Ikoko ti ao fi se, ao bu Omi Ogi lelori ti o po dada, ao se (Boil) ti o jina dada fun bi Ogun/Ogbon Iseju (20/30min).

LILO RE
======
Ao bu Eyi ti a femu ni Odiwon Idaji stainless cup kan, ao bu Eyi ti ao Fin (Steaming) sinu ike ti o ba tobi dada, ao koko fin agbo yi fun bi Iseju mewa (10min), leyin na ao da omi Tutu lasan sinu re leyin ti a ti fin (Steaming) tan, ao lofi we.

Bayi ni ao se mase ni owuro ati Ale fun ojo meta, tabi ju belo.

Mi o fe mo bi Aisan "IBA JEFUN-JEDO (TYPHOID) na se fe le to, mofi Oba ti o da Ewe Ati Egbo bura, Aisan na o lo patapata.

IMORAN: Eje ki a ri daju pe a nse imototo (Sanitation) Inu Ile Ati awon Ayika wa gbogbo, Nitoripe Latara aikosi Imototo ni Aisan yi ngba wole ooo.

Mobe Olohun Oba, Eyi ti o kere ati eyi to tobi ninu Aisan, Ki o mafi se Enikokan wa oo🙏

Iwo na bawa share re, lati gba Emi la (save soul).

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

OSHOLE JENRAYEWA================●Eja Abori Ako & Abo●Ewe Iyalode Pupa●Ewe Iyalode Funfun ●Igba Oni Koko●Miss Paris ●Oti ...
22/07/2025

OSHOLE JENRAYEWA
================
●Eja Abori Ako & Abo
●Ewe Iyalode Pupa
●Ewe Iyalode Funfun
●Igba Oni Koko
●Miss Paris
●Oti Awon Agba 1
●Ose Dudu

OSHOLE je Ona Igbiyanju lati laa ninu Aye, Opo inu ile ni oti daru latara Aikosi Owo (Money), Beena ni Opo Igbeyawo ni Oti Tuka latara Aikosi owo, Opo Oko (Husband) ni o tidi Eni ti kole pase mo ninu Ile mo.Orisirisi omo ni Eto Eko won ti Taku si ona Nipase Aikosi Owo, Elomiran sa kuro ni ilu ti won ti bi, ti o si Kori lo si ilu miran Lati lo gbiyanju oro aje, Sugbon sibesibe Pabo ni Gbogbo re njasi.
Opo ni o pate oja kale ti won o bawon na, eyi je ki o yewa pe, Owo (Money) Je okan pataki ti a fi nri Aye se Leyin Alaafia ati Ifokanbale.

Opolopo ni o ni Awon Oluranlowo ti o le yo won kuro ninu Ise Ohun Iya (Poverty) ni egbe, sugbon ti won ko se Iranlowo fun won, Elomiran ni Egbon tabi Aburo, ti Eledumare segi ola fun won, ti won le yo won kuro ninu ise (Poverty) sugbon ti won o ya si won rara.

Owe Yoruba sope:
"Ajumobi o kan T'aanu"
Bi ao bari Eni feyin ti, Bi ole laari😒

Lododo! O kiise Ole (Lazy), sugbon kobadara ki

Owo (Money) ni nfuni ni Ifokanbale, Owo lonni di Alase nibi Gbogbo,Owo ni funi layo ati Idunu, Owo ni a fi nsoko Obinrin ninu ile, Owo ni a fi ndi Eni Giga.

Mobe Olohun Oba Ti o ni Buruji lodo, ki o tari Buruji si Gbogbo wa o 🙏🙏🙏

BI AOSESE
Ao pa Eja Abori mejeji yi, ao da Aya won dele ninu Ape Ijogun, ao to owo ti o ba wuwa meta lelori, ao ko Ewe Iyalode mejeji lelori, ao fi Odidi atare kan si, ao jo Gbogbo re papo, ao pin Ise yi si Ona meji, ao po okan mo Ose dudu, ao wafi lofinda Miss Paris yi po, ao ni fi Omi kankan si ose yi o, Ao ko sinu Igba Onikoko na.

Ao da Ekeji sinu Oti na, ao ju Owo odidi kan sinu re .

LILO RE
Ao ma we Ose yi ni Ojojumo pelu Adura pe:
"OBA TONI OWO, WATARI OWO SI ODO MI O"
Ao mamu Oti na ti a bati we ose na tan pelu gbolohun re pe:
"OTI KII TI,OTI KII TEE, KINMASE TI, KIMMASE TE".
"OMI KII TI, OMI KII TE, KINMASE TI, KINMASE TE".

Pelu ogo olohun oba ti o seda Ewe Ati Egbo Ti o ba nlo ise yi, Aje o ma wa o kiri ni.

Oba ti o ni Aje lodo, ki o tari Aje si Gbogbo wa🙏

Fun Ibere Tabi Ohunkohun
08038692880

Shout out to my newest followers! Excited to have you onboard! Morewa Oyinlola, Kolawole Opeyemi Lasisi, Adisa Oketayo, ...
21/07/2025

Shout out to my newest followers! Excited to have you onboard! Morewa Oyinlola, Kolawole Opeyemi Lasisi, Adisa Oketayo, Olaide Arowofela Rasheed, Nureni Tiamiyu, Omotosho Ojo, Ade Kunle, Ọjọgbọn Bánúso, Hadi Tchalla, Adeshina Dolapo

OSE ASIRIBIBO ASINA=================Alakan (Crab) 3Oga Gbigbe (Carmelion) 3Atare Odidi (Aligator Pepper) 3Ewe Rere Tutu ...
17/07/2025

OSE ASIRIBIBO ASINA
=================
Alakan (Crab) 3
Oga Gbigbe (Carmelion) 3
Atare Odidi (Aligator Pepper) 3
Ewe Rere Tutu (Fresh Favourable Leaf)

Ti Oro Eda ba dojuru, ti Eda wa nsise Bi Erin ti o wa nje Ije Enliri, Tabi iwo ti Oko owo (Business) re o lo dede mo, Tabi Atije Atimu lodi Isoro fun Eda, mase damu kiri mo o, Gbiyanju ki o bami se Ise Yi, Odamiloju pe wa ma fi ope fun Oba ti o seda Ewe Ati Egbo ni.

BI AOSESE
Ao to Alakan meteta sinu Ape Ijogun, ao wa to Oga meteta yen le Lori, ao to Atare yen na Lelori, Ao wa fi Ewe Rere yen bo Ise yi Lori ti koni han mo rara, odi Jijo Papo, Ti a ba jo tan, Ao tun lo loju olo, ao wa po mo Ose Dudu Aladin.

LILORE
Ao mafi Ose yi we ni owuro kutu ki Orun o Toyo ni ojo meta-meta, mofi Oba ti o dami se Eri, Ti o ba nlo Ise yi wa ma fi Ope fun Oba na ni gbogbo Igba ni.

Mobe Olohun Oba Ti o ni Ariski lodo, ki o tari Arisiki si Gbogbo wa ooo🙏

Iwo na bami share re, ki awon Elomiran na le je Anfani re.

Fun Ibere Tabi Ohun miran
08038692880

IWULO IRUKERE AGBADO(HEALTH BENEFITS OF CORN SILK)=========================●Fun Arun Iseto (Prostate)●Fun Arun Ibalopo (...
15/07/2025

IWULO IRUKERE AGBADO
(HEALTH BENEFITS OF CORN SILK)
=========================
●Fun Arun Iseto (Prostate)
●Fun Arun Ibalopo (Std Infection)
●IFUNPA GIGA (HIGH BLOOD PRESSURE)
●Apoju Ora (Burn Fat)
● Aisan Atogbe (Diabetes)
●Omode/Agbalagba Ti o ntosile. (Bedwetting)
●Ara yiyun (Rashes)
●Esuke (Hiccup)

IRUKERE AGBADO (CORN SILK) je Ohun ti onse Opolopo Anfani Fun Itoju Ailera (Health) wa, Toripe Oni Oniruru Awon Eronja Afaralokun ati Eronja Amu Adinku ba Irora (Pains).

Ninu Iwadi Imo Ijinle, Ari Aridaju pe IRUKERE AGBADO (CORN SILK) yi nsise fun Itoju Oniruru Arun ati Iwosan ti o ba ndamu omo Eniyan ninu Ago Ara wa, Beena sini Iwadi Imo Ijinle fi Idi re munle pe Siliki Agbado yi le se Akoba fun Alaboyun, fun idi eyi ko dara rara ni LILO fun Alaboyun, Bakana Obinrin ti o nwo omo lowo.

Oniruru ona ni a le gba lo SILILIKI AGBADO yi fun Titoju Iwosan Tabi Arun ninu Ago Ara wa.

●AISAN IBA (MALARIA FEVER)
Ki eni ti o bani Aisan Iba o ma se Irukere Agbado lagba pelu Ewe Akintola fun bi Ogun Iseju (20min), ki a maa mu ni Idaji Ife kookan lowuro ati Lale fun Ose kan gbako.

●ARUN IBALOPO (STD INFECTION)
Kiise ibi ibalopo nikan ni ati ma nko Arun yi o, Paapa julo, Awon ona ti a ngba ko Arun yi po gan.
Ki eni ti Arun yi ba nda laamu o wa SILIKI AGBADO yi, ki a wa gun ni Tutu pelu Eru Alamo (Balck Pepper),Baaka (Sauvages), ati Ataile (Ginger), ao gun Gbogbo re papo ao wa sa ki o gbe. Ao mafi mu Ogi (pap) Gbigbona laaro ni ekan lojumo.

●APOJU ORA/ARA SISAN JU
(TOO MUCH FAT)
Ki eni ti o bani Apoju Ora tabi Apoju Ara Sisan o wa SILIKI AGBADO YI ki o po dada, ki o wa sa lasan bee ki o gbe, ki o ma fi po TEA mu ni ojojumo, ao ma se (boil) ao si ma se (filter).

●ARUN ISETO (PROSTATE)
Ki eni ti o bani Arun yi o wa SILIKI AGBADO yi ki o po, ki a sa ki o gbe, ki a wa gun lasan bee, ki a wa ha fofo olokun (Culttlefish Bone) si leyin ti o ti gbe tan. Ki a ma mu sibi kan laro ati Ale pelu omi Omi Gbigbona leyin tia ti jehun tan.
Eni na o maribi se Igbonse dada, Yi o si ma fo (Clean) awon idoti inu Apo ito eni danu.

●ARA YIYUN/KOKORO ARA (RASHES).
Ki eni ti Ara ba ma nyun tabi awon Kokoro Ara o lo wa SILIKI AGBADO yi ni Tutu, ki a ma se (Boil) lasan ki o jina ki a mafi agbo yi we (bath) ki a sima bu iyo sibi kan sinu omi iwe na.

Kiise Gbogbo Anfani ti o wa lara SILIKI AGBADO yi ni a le Salaye re tan, sugbon ao tun ma tesiwaju nigbamiran.

Gbogbo wa o nifi Aisan/Arun logba 🙏

Iwo na bami share re fun Anfani Elomiran!

Fun Ibere Tabi ohun miran
08038692880

Address

Lagos

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when BaBa ASEYORi posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Practice

Send a message to BaBa ASEYORi:

Share

Share on Facebook Share on Twitter Share on LinkedIn
Share on Pinterest Share on Reddit Share via Email
Share on WhatsApp Share on Instagram Share on Telegram